Èèyàn kan jóná kọjá mímọ̀ lẹ́yìn tí iná sọ lára ‘generator’ ní Victoria Island, Eko

O kere tan, eeyan kan ti jade laye lẹyin ina kan to ṣẹyọ lagbegbe Adeola Odeku, ni Victoria Isaland, niluu Eko.
Iroyin ni ọpọ eeyan lo farapa nibi ijamba ina naa to waye niwaju ile iṣẹ ifowapamo Providus Bank ni owurọ ọjọ iṣegun.
Oṣoju mi koro kan ṣalaye fun akọroyin BBC pe dede agọ mẹwa kọja iṣẹju marun ni ina naa bẹrẹ, ti eeyan mẹsan si farapa yanayana.
Gẹgẹ bii ohun ti oṣoju mi koro naa sọ, oku eeyan meji si wa labẹ tanki epo to fa ina ọhun, ti wọn ti jona raurau.
Bawo ni ina naa ṣe ṣẹyọ?
Ileeṣẹ panpana ipinlẹ Eko sọ ninu atẹjade kan pe ẹrọ amunawa ‘generator’ lo ṣokunfa isẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti adari ileeṣẹ naa, Adeseye Magaret fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ẹka ileeṣẹ naa to wa ni Oba Oniru lo pana rẹ.
O ni “Ara ẹrọ ‘generator’ nla ti wọn n tu ṣe lọwọ ni ina ọhun ti ṣẹyọ.”
“Ina to sọ lara ẹrọ generator naa to wa ninu ọgba ile ifowopamọ kan tun ran ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Saloon ti ileeṣẹ ọlọpaa Rapid Respond Squad ti ilu Eko to wa niwaju ile ifowopamọ naa.
“Amọ o ṣeni laanu pe a ri oku ọkunrin kan to ti jona kọja mimọ, a si ti gbe oku naa le agọ ọlọpaa to wa ni Bar Beach lọwọ.”
Margaret pari ọrọ rẹ pe ina ko kan ara ile alaja mẹrin ti generator rẹ lana.
Bẹẹ naa ni ori ko awọn agbofinro RRS to wa nibẹ yọ lọwọ ina ọhun.












