‘Ọjọ́bọ là ṣì fi ìpàdé àdúrà wákàtí méjì sí fún ìlera Akeredolu kí a tó gbọ́ ìròyìn ikú rẹ̀ l’Ọ́jọ́rú’

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Arakunrin Akeredolu/X

Awọn eeyan ipinlẹ Ondo, ilu Ọwọ, orilẹede Naijiria ati jakejado agbaye si ṣe n daro lori iku gomina ipinlẹ Ondo, to tun jẹ odu agbẹjọro ati amofin agba, Oluwarotimi Akeredolu, SAN.

Awọn eeyan to sunmọ ṣi n sọ wi pe bi ala ni ọrọ naa ṣi jẹ loju awọn.

BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu Ọwọ tii ṣe ilu abinibi Gomina Rotimi Akeredolu nibi ti gbogbo rẹ ti pa lọlọ ti ọpọ awọn olugbe ilu naa ṣi n kẹdun iku rẹ gẹgẹbi ẹni to ‘ṣe iṣẹ lọpọlọpọ fun idagbasoke ilu Ọwọ”.

Ọjọ Iṣẹgun la ṣi lọ si ile rẹ lati gbadura fun ilera rẹ - Alaga CAN ipinlẹ Ondo

Aworan ijọ ti Akeredolu n lọ ni ilu Ọwọ

Alufaa Raphael Agboola ti o jẹ alaga àjọ tó n ri si ẹgbẹ awon ọmọlẹyin Kristi n'ipinle Ondo so wi pe ni nnkan bi ago mẹjọ abọ ọjọ Iṣẹgun ni oun ati awon alufaa meje kan kuro ni ile gomina nibi ti won ti lọ gbadura fun un.

Alufaa Agboọla to sọ pe oun ṣi wa ninu ijaya ni Ọjọbọ tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn ni awon ti yasọtọ fún akanṣe adura oni wakati meji lati ago mejila di agọ meji ọsan fun Akeredolu.

Agboola ti o tun je oludari ile ìjósìn Gomina Akeredolu St.Andrew's Cathedral Imola, Ọwọ sọ pẹ gbogbo awon alakale ìjọ ọhun ni won ti so rọ bayii.

Awọn olugbe ilu Ọwọ kan

Aafin ilu Ọwọ wọgile gbogbo eto ifinijoye to yẹ ko waye lọjọru nitori iku Akeredolu

Aworan Aafin Ọlọwọ ti ilu Ọwọ

Ni aafin Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, BBC News Yoruba gbọ pe kete ti iroyin iku Akeredolu jẹyọ, gbogbo eto nipa ifinijoye ti o yẹ ko waye l'Ọjọru ni won so rọ.

Ẹni to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pẹ "oni ni ifinijoye fun Ayodeji Daniel Olupona gẹgẹ bi oloye giga irato Ọlọwọ ti ilu Ọwọ ṣugbọn nigba ti won jo de afin laaro oni, ṣe ni awon alaṣẹ afin da won pada.''

Bakan naa ni Ọwọ recreational club ninu eyi ti Gomina Akeredolu jẹ baba isale ati omoegbe ni lati sunipade apapọ ọlọdọọdun wọn to yẹ ko waye ni Ọjọru siwaju ni kete ti iroyin iku Akeredolu jade sita.

Awọn Ọlọkada ni ilu Ọwọ

Akọwe ẹgbẹ naa Onimọẹrọ Rafiu Ojawoye ṣalaye pe Akeredolu jẹ ọkan gboogi ninu egbẹ naa lati ọjọ pipẹ.

" Ki Akeredolu to di Gomina ni lo ti je ọmọ egbe wa, ilana ẹgbe wa si ni pe Gomina ni o gbọdọ jẹ baba isalẹ eyi lo mu ki Akeredolu di ipo naa mu ko to jade laye.

Inu wa ko dun rara fun isele aburu yii, adura wa ni pe ki Ọlorun tẹ ẹ sì afefe rere."