Ọ̀nà wo ní ọgá iléeṣẹ́ Binance Najeem Anjarwalla tó wà ní àhámọ́ ONSA ṣe di àwátì?

Aworan Nadeem ati ami idanimọ Binance

Oríṣun àwòrán, Binance

Ileeṣe oniṣowo Crypto nii Binance ti fidi ọrọ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC pe ọkan lara awọn alaṣẹ rẹ ti o wa ni ahamọ awọn alaṣẹ lorileede Naijiria ko si lọdọ wọn mọ.

Ọrọ yi n jade lasiko ti iroyin gbode pe o ti rapala salọ kuro ni Naijiria.

Najeem Anjarwalla to ṣe pe o ni iwe irinna pasipọti ti ilẹ Gẹẹsi ati ti Naijiria ni awọn alaṣẹ Naijiria mu loṣu to kọja pẹlu akẹgbẹ rẹ kan Tigran Gambaryan.

Awọn alaṣẹ lorileede naa lawọn n ṣe iwadii wọn lori ẹsun pe wọn lo ọgbọn alumọkọrọyi lati ma ṣe san owo ori fun ijọba.

Ọkan lara awọn agbẹnusọ Binanace sọ pe ‘’wọn jẹ ko di mimọ funwa pe Nadeem ko si ni ọdọ awọn alaṣẹ Naijiria mọ.Ohun to si jẹwa logun bayi ni alaafia oṣiṣẹ wa taa si n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ ni Naijiria lati yara yanju ọrọ yii.’’

Ẹwẹ,awọn alaṣẹ Naijiria ti fẹsun kikọ lati san owo ori kan ileeẹ Binance nileẹjọ giga kan ni olu ilu ilẹ naa Abuja.

Ninu awọn ti wọn fẹsun kan si ni Ọgbẹni Anjarwalla wa.

Ileeṣẹ to n gbowo ori lorileee Naijiria, Federal Inland Revenue Service (FIRS) fẹsun kan ileeṣẹ Binance pe o kọ lati san owo ori to yẹ ko san bẹẹ si lo n lẹdi apo pọ pẹlu awọn alabara rẹ lati ma ṣe san owo ori to yẹ lati oju opo rẹ si akoto ijọba.

Loṣu to kọja lawọn alaṣẹ Naijiria foju si ileeṣẹ naa lara lorileede ọhun ti wọn si ni awọn to n ṣe fayawọ owo n lo oju opo naa ati fi hu iwa to mọ ṣiṣe atilẹyin ati iranwọ owo fun awọn iwa agbesunmọmi.

Banki apapọ Naijiria naa tun sọ pe idokowo to le ni biliọnu mẹrindinlọgbọn Naira lo gba oju opo crypto naa kọja lati ọna to ruju.

Wọn tun sọ pe oju opo yi n ṣe idunadura ọna ẹburu nipa paṣiparọ owo dọla si Naira eleyi to lọwọ ninu bi Naira ṣe dẹnukọlẹ lẹgbẹ Naira.

Naijiria to ni eto ọrọ aje to tobi julọ nilẹ Africa ti n koju ipenija ọrọ aje ti ko rọsọmu ti ko si ṣẹyin owo Naira to dẹnukọlẹ ati ọwọngogo nkan lawujọ.

Nibi ti gbogbo eleyi ti n ṣẹlẹ ni awọn alaṣẹ ti fofin mu ọga ileeṣẹ Binance lẹkun iwọ oorun ilẹ Africa, Najeem Anjarwalla ati Tigran Gambaryan ọmọ orileede Amẹrica to n mojuto ẹka ṣiṣe ibamu pẹlu ofin idunadura ileeṣẹ naa.

Kete tawọn mejeeji balẹ si Naijiria ni wọn mu wọn lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2024.

Aworan Najeem Anjarwalla

Oríṣun àwòrán, Binance

Awọn alaṣẹ sọ pe ki Binance darukọ awọn ọmọ Naijiria to n doko owo loju opo wọn.

Ileẹjọ faaye gba ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu EFCC lati le fi awọn ọga ileeṣẹ yi mejeeji si ahamọ fọjọ mẹrinla ki wọn to wa pada sunjọ siwaju si lori fifi wọn si ahamọ.

Ọjọ kẹrin oṣu Kẹrin lo yẹ ki Anjarwalla foju ba ile ẹjọ ṣugbọn iroyin pe o ti na papa bora lu sita ni nkan bi wakati mẹrinlelogun.

Awọn ileeṣẹ iroyin kan labẹle ni Naijiria n jabọ pe o tọrọ aaye lọwọ awọn to n sọ wipe oun fẹ lọ kirun Jimọ ṣugbọn ko pada wa lati igba naa.

A gbọ pe awọn alaṣẹ ti gba iwe irinna pasipọti ti ilẹ Gẹẹsi rẹ lọwọ rẹ ṣugbọn wọn ko mọ ibi ti iwe irinaa ti Kenya rẹ wa.