Wasiu Ayinde sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ànìkànjọpọ́n tí onílù rẹ̀ kan fi kàn-án

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Lati bi ọṣe diẹ sẹyin ni iroyin bi ọkan lara onilu tẹlẹ fun gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti orukọ rẹ n jẹ Kunle Ayanlowo ṣe fẹsun kan an pe, bi ẹru lo ṣe ṣe oun ati awọn onilu akẹgbẹ rẹ lasiko ti oun wa labẹ rẹ.

Ayankunle ninu ifọrọwerọ kan, sọ pe gbogbo igba ni K1 ma n gba iwe irinna awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ fun idi to jẹ pe oun nikan lo mọ.

O fẹsun kan K1 pe o ni igba kan to paṣẹ fun oun lati pada sile lasiko ti oun lọ si ile iwosan fun itọju.

Ayankunle tẹsiwaju pe ọdun mejilelọgbọn ni oun lo labẹ agba olorin Fuji naa, to si jẹ pe oun ko ri nkankan kojọ.

O ni aisan ọgbẹnu n ba oun finra fun igba pipẹ, to si ni ki awọn eeyan mu K1 so ti ohunkohun ba sẹlẹ si oun.

“O ni wahala ni Ayankunle, o ti lọ, o tun ti wa pada"

Nigba to n fesi si ẹsun naa, Wasiu Ayinde ni oniwakuwa, alaimoore ni Ayankunle, to si fẹran owo pupọ.

K1 salaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu GoldmyneTV pe oun ka Ayankunle Ayanlọwọ gẹgẹ bii ẹni to fẹran wahala.

O tẹsiwaju pe oun ni adehun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ lori bi awọn yoo ṣe ma pin owo, ti ko si nkankan to jọmọ pe oun n fiya jẹ ẹnikẹni.

O ni ọpọ igba ni oun ti lọ yawo lati ri pe oun mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ oun.

“Nigba ti mo ba yawo lati mu ilọsiwaju ba awọn ọmọ ẹyin mi, ko si ẹni to ri mi, owo ajọ, ati awọn owo mi nitori mo fẹ mu awọn ọmọlẹyin mi rin irinajo.

“Adehun to wa laarin emi ati awọn ọmọ ẹyin ni ida ọgọta si ida ogoji lati bẹrẹ sugbọn nigba ti wọn pọ si, mo ṣe atunṣe si owo pinpin, mo sọ ọ di ida aadọta fun onikaluku.

“Emi ni ma ṣe gbogbo nnkan, mo ma kọrin, koda mo le ma gba owo lọwọ awọn eeyan mii, sugbọn mi o ni sọ fun awọn ẹgbẹ."

"Idi ti mo fi n gba iwe irinna awọn ọmọ ẹgbẹ re"

K1 ni idi ti oun fi ma n gba paali iwe irinna awọn ọmọ ẹgbẹ nigba ti wọn rin irinajo lọ si oke okun ko sẹyin aṣakasa to kun ọwọ ọpọ wọn.

O ni ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oun lo ti sa lọ ti wọn ba ti de si oke okun, to si n ṣe ọpọlọpọ akoba.

K1 ni ko rọrun lati ṣe agbatẹru ọmọ ẹgbẹ, ti oun si ti n ṣe lati bi aadọta ọdun bayii.

“Irinajo lọ si ilẹ yoorupu ti a lọ gbẹyin, ti a ba de ẹnu ibode pe a fẹ gba iwe irinna, wọn bi wa pe awọn ti a ko lọ gbẹyin nkọ, sugbọn wọn ti salọ.

“Ti a ba mu eeyan mi wọle, wọn ma bi wa pe awọn ti a ko lọ tẹlẹ nkọ, ṣe a fẹ sọ fun wọn pe wọn ti salọ ni, niṣe ni mo ma n ṣo fun pe wọn ti kuro ninu ẹgbẹ ni sugbọn lẹyin iwadi wọn ma ri pe wọn ti salọ.

O ni idi ti oun tun fi n gba iwe irinna wọn, ni ki wọn ba ma le sọnu, ati lati lo o fun gbigba iwe aṣẹ lati sisẹ ni oke okun.