Binance fòpin sí ìdókoòwò naira lójú òpó rẹ̀, kí ni èyí túmọ̀ sí?

Oríṣun àwòrán, Binance/Nairametrics
Ileeṣẹ idokoowo cryptocurrency, Binance ti kede pe oun yoo fopin si ajọṣepọ rẹ pẹlu awọn oniṣowo crypto ni Naijiria.
Binance lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun.
Igbesẹ naa lo n waye lẹyin ti ijọba apapọ Naijiria fẹsun kan ileeṣẹ ọhun pe owo ti awọn araalu fi n ṣowo loju opo ayelujara rẹ n ṣakoba fun agbara owo naira.
Binance ni ileeṣe oniṣowo Crypto to tobi julọ lagbaye, o si ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria to n ba a dowopọ pe, ajọsẹpọ wọn yoo dopin lọjọ kẹjo, oṣu Kẹta, ọdun 2024.
Araalu ko ni le sanwo wọle tabi gba owo jade lori Binance pẹlu naira
Igbesẹ Binance tuntun yii yoo ṣakoba fun awọn ọmọ Naijiria, to n gbe ni Naijiria to si n fi owo naira ṣowo lọdọ rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Binance ko fofin de awọn ọmọ Naijiria to n ba dowopọ, awọn to ba fẹ ta tabi ra crypto nibẹ ni lati wa ọna mii tabi lo owo orilẹ-ede miran to yatọ si Naira lati fi dokowo.
Amọ ṣa, kii ṣe Binance nikan ni ileeṣe to n ṣowo crypto ni Naijiria, oniruru ileeṣe mii ni wọn ti n ṣowo crypto, ti awọn ọmọ Naijiria si n lo wọn.
Lara awọn ileeṣẹ naa ni Kucoin, Bybit, Remitano, Latoken, Mexc, OKX, Coinbabse, Yellow Card, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O di ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta
Ṣaaju ni ijọba Naijiria ti kọkọ fi ṣikun ofin mu awọn alaṣẹ Binance meji ni Naijiria.
Ijọba ni wọn n ṣe onigbọwọ awọn to n ko owo tabua pamọ lọna ti ko tọ ọ.
Lẹyin naa ni ijọba ni ki wọn san owo itanra ti iye rẹ to bilọnu mẹwaa naira.
Wayi o, lẹyin ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2024, gbogbo owo naira to wa ni akata Binance ni wọn yoo paarọ si USDT.
Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fierongba wọn lede nipa igbesẹ ijọba apapọ, eyii to fa igbesẹ Binance yii.















