Wo bí ètò pínpín oúnjẹ tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fún àwọ̀n ọmọ Naijiria yóò ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ Naijiria ti kede pe awọn yoo bẹrẹ si ni pin ounjẹ kaakiri orilẹede naa, lati tako iṣoro ọwọngogo ounjẹ to gbode lasiko yii.
Minisita fun eto ọgbin ati ipese ounjẹ, Abubakar Kyari lo kede igbeṣe yii lọjọ Aje.
Kyari salaye pe oun mọ bi nnkan ṣe nira fun ọpọ awọn ọmọ Naijiria lasiko yii, to si n fi n da wọn loju pe ijọba n sa gbogbo akitiyan rẹ lati ri pe wọn wa ojutu si iṣoro ọwọngogo ounjẹ.
“Pẹlu bi nnkan ṣe nira yii, mo n fi dayin loju pe adehun wa si ilu ko yipada.
“A o bẹrẹ si ni pin ounjẹ toto ẹgbẹrun mejilelogoji toonu, eyi ti Aarẹ Tinubu ti buwọlu, kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogogi ni ọsẹ yii."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Minisita naa sọ pe ijọba n sisẹ pọ pẹlu ajọ to n mojuto isẹlẹ pajawiri, NEMA, ati awọn ẹsọ alabo DSS lati ri pe awọn ounjẹ yii de si ọdọ awọn araalu to nilo rẹ.
Bakan naa lo kede pe toonu irẹsi mejidinlọgọta ni awọn fi ransẹ si awọn ọja kaakiri.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti sun kan ogiri bayii latari ọwọngogo ounjẹ to gbode.
Iroyin ni nnkan bii idaji araalu lo n gbe ninu isẹ ati oṣi nitori bi wọn ko ṣe ri ounjẹ igba mẹta jẹ lojumọ.
Gbogbo rogbodiyan naa ko ṣẹyin igbesẹ ijọba apapọ lati fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro ati bo ṣe ja agbara owo naira silẹ.
Eyi ti n mu ki ara kan ọpọ araalu, ti awọn mii si n lọ fọ ibudo ti ijọba n ko ounjẹ pamọ si ki wọn le bọ ara wọn atawọn mọlẹbi wọn.














