Wo àwọn nǹkan tó wà nínú ìwé àdéhùn okòwò tí Naijiria tọwọ́ bọ̀ pẹ̀lú Qatar

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Bọla Tinubu, ti tọwọ bọ iwe adehun ajọṣe pẹlu orilẹ-ede Qatar.
Eyi waye nigba to ṣabẹwo si olori ilu naa, Sheikh Tamim bin Hamad Al Thani, ni Doha, olu ilu orilẹ-ede naa, lọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2024.
Agbẹnusọ Aarẹ Tinubu lori eto iroyin, Ajuri Ngelale lo fi eyi lede ninu atẹjade to fi kede àbọ̀ Qatar naa, ni Doha ti Tinubu ti pade Emir Tamin.
Lara awọn ẹka ajọṣepọ ti adehun naa kan ni ipese iṣẹ, idokowo, riro awọn ọdọ lagbara, eto ẹkọ, ati irin ajo afẹ.
Awọn ẹka yooku ni ere idaraya, iwakusa ati igbogunti oogun oloro.
Ninu ọrọ Aarẹ Tinubu, o ṣalaye pe Naijiria ni awọn ọdọ to kun oju oṣuwọn ni gbogbo ẹka.
Aarẹ sọ pe anfaani nla ni yoo jẹ fun Qatar, bi wọn ba le waa da ileeṣẹ silẹ ni Naijiria.
O ni nnkan amuṣọrọ pọ lorilẹ-ede yii, awọn eeyan ibẹ si le ni igba miliọnu daadaa.
Tinubu sọ pe loootọ ni Naijiria n la awọn iṣọro kan kọja lasiko yii lẹka ọrọ-aje, ṣugbgọn igbesẹ ti yoo ṣẹgun iṣoro naa ti wa nilẹ.
O ni Qatar ko ni i kabaamọ to ba waa ba Naijiria dowopọ.
‘’A ó ṣàbẹ̀wò sí Naijiria lẹ́yìn ààwẹ̀ Ramadan, làti mọ ohun tí a màa ṣe’’

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale
Nigba to n fesi, Sheikh Tamin bin Hamad Al Thani, Aarẹ Qatar, sọ pe oun yoo ran ikọ kan wa si Naijiria lẹyin aawẹ Ramadan, lati waa wo ohun ti awọn ba le ṣe.
Emir Tamin sọ pe oun wa si Naijiria ni 2019, oun si ri i pe ọlọpọlọ pipe to fẹran iṣẹ aje lawọn eeyan ilu naa.
O ni ohun ti Aarẹ Tinubu ba wa yii jẹ itẹwọgba, oun si fẹran rẹ.
O wa a ni kawọn to o da ileeṣẹ silẹ nibi kan, awọn yoo wo ohun ti yoo tibẹ jade.
O fi kun un pe owo ara oun kọ ni oun yoo fi da ileeṣẹ silẹ ni Naijiria, owo irandiran awọn ọmọ Qatar to n bọ lọjọ iwaju ni.
Eyi lo ni o fa a to fi yẹ ki ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ ko lọ ki iṣẹ naa too bẹrẹ.
Lẹyin eyi lo kọwọ bọ iwe adehun ajọṣe laarin orilẹ-ede mejeeji.
Wale Ẹdun, Minisita fun eto iṣuna Naijiria ni Aarẹ Tinubu yan lati ba awọn ikọ Qatar naa ṣe lorukọ Naijiria bi wọn ba de.
Bi ẹnikẹni ba beere owo ẹ̀yin lọwọ yin, ẹ fi ẹjọ rẹ sun mi- Tinubu

Lati fidi ajọsẹpọ yii mulẹ gidi, Aarẹ Tinubu sọ fawọn olokoowo Qatar, pe bi ẹnikẹni ni Naijiria ba beere owo ẹyin lọwọ wọn, ki wọn fi to oun leti.
"Ẹ ma ṣe fun ẹnikẹni lowo ẹ̀yìn ninu awọn eeyan wa, bi wọn ba beere lọwọ yin, tabi ti wọn gba a, ẹ fi ẹjọ wọn sun mi. Ẹ maa ni anfaani lati ba mi sọrọ.’’














