Ṣé lóòtọ́ ni UAE ti bẹ̀rẹ̀ sí fún àwọn ọmọ Naijiria ní ‘Visa’ padà? Oun tí a mọ̀ rèé

Baalu ileeṣẹ Emirates

Oríṣun àwòrán, FLY EMIRATES

Ijọba Naijiria ti sọ pe irọ patapata ni iroyin kan to ni, ijọba United Arab Emirates, ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de fi fun awọn ọmọ Naijiria ni iwe irinna lati wa si orilẹ-ede wọn.

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni ijọba UAE fi ofin de Naijiria ati awọn orilẹ-ede mọkandinlogun mii ni Africa.

Ṣugbọn ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ni iroyin kan jade si ori ayelujara, eyi ti awọn ileeṣẹ iroyin kan naa gbe pe, ijọba UAE ti wọgile ofin naa.

Wakati diẹ lẹyin ti iroyin naa jade, ni oludamọran pataki fun Aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga, kede pe ayederu iroyin ni.

Ninu ikede to fi si ori ayelujara X rẹ, lo ti sọ pe iwe ikede to n lọ kaakiri nipa ofin naa, ko wa lati ọwọ ijọba Naijiria tabi UAE.

Ninu iwe ikede to jade ọhun ni wọn ti sọ pe ijọba Naijiria ati ti UAE, ti fi ohun kan kede pe idagbasoke ti ba ajọṣepọ wọn, nipa fifi aaye gba awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrinajo lọ si orilẹ-ede naa lati wọle, bẹrẹ lati ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2024.

Bakan naa ni awọn to fi iroyin naa sita sọ pe awọn ọmọ Naijiria le lọ si oju opo ayelujara ileeṣẹ ilẹ okeere fun UAE, lati bẹrẹ igbesẹ fun gbigba iwe irinna.

Amọ abẹwo ti BBC Pidgin ṣe si oju opo naa fihan pe, ko si nnkan to jọ ọ.

Igba akọkọ kọ niyii ti iru iroyin bẹẹ jade pe UAE ti fi opin si ofin ọhun.

Ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ni agbẹnusọ fun aarẹ, ajuri Ngelale, fi atẹjade kan sita pe orilẹede mejeeji ti fẹnuko lati gbẹsẹ kuro lori ofin to tako fi fun awọn ọmọ Naijiria ni iwe irinna lọ si UAE, lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe ipade pẹlu pẹlu Aarẹ Mohamed bin Zayed al Nahyan, lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023.

Ṣugbọn ijọba UAE sọ lori itakun agbaye wọn pe, irọ ni. Wọn ni ijiroro nipa bi orilẹ-ede mejeeji yoo ṣe ni ajọṣepọ ni awọn olori mejeeji ni, kii ṣe lati ṣe eto bi wọn ṣe ma a fun awọn ọmọ Naijiria ni ‘visa’ pada.

Bawo ni wahala irinajo ṣe bẹrẹ laarin Naijiria ati UAE?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdun 2021 ni rogbodiyan ti n rugbo o bọ, paapaa ni ẹka irinajo oju ofurufu.

Ninu oṣu Keji, ọdun 2021, ijọba Naijiria din iye igba ti ileeṣẹ ọkọ ofurufu Emirates to jẹ ti UAE, le ma a ko ero ni Naijiria, lati mọkanlelogun si ẹyọkan l’ọsẹ.

Ijọba sọ pe oun gbe igbesẹ naa lati gbẹsan bi UAE ṣe din ti ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace, to jẹ ti ọmọ orilẹ-ede Naijiria, lati mẹta l’ọsẹ si ẹyọkan.

Igbesẹ ti ijọba Naijiria gbe yii mu ki Emirates airline fi opin si gbigbe ero jade tabi wọle si Naijiria, fun ọpọlọpọ ọsẹ.

Ṣugbọn wọn tun pada bẹrẹ iṣẹ lẹyin ti ijiroro waye laarin orilẹ-ede mejeeji.

Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, Emirates Airline kede pe awọn ti da irinajo gbogbo ni Naijiria duro, bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an.

Wọn ni awọn ṣe bẹẹ nitori pe awọn ko ri owo awọn to ha si Naijiria gba.

Lẹyin ti Aarẹ Tinubu de ipo, o ṣe ileri ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2023, pe awọn ko ni i pẹ yanju aawọ naa.

Amọ titi di asiko yii, UAE ṣi kọ̀ lati ma a fun awọn ọmọ Naijiria ni visa.