'Tí àsìkò bá ti tó, ó ti yá nìyẹn' Fọ́nrán ìkẹyìn Mr Ibu

Aworan Mr Ibu

Oríṣun àwòrán, MR IBU/INSTAGRAM

Fọnran kan to bọ sori ayelujara safihan igba ikẹyin gbajugbaja adẹrinposonu, John Okafor, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Mr Ibu.

Mr Ibu jade laye lọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2024 lẹyin to ṣe aisan ọlọjọ pipẹ.

Fọnran ọhun to jẹ isẹju kan lo safihan bi Mr Ibu ṣe n sọrọ lasiko to wa lori idulẹ aisan, to si n kan sara si gbajugbaja olorin takasufe, Paul Okoye, ẹni ti ọpọ si RudeBoy Psqaure fun bi o ṣe gba ruku ti.

Ninu fọnran naa Mr Ibu ni “Rudeboy, mi o mọ bi ma ṣe bẹrẹ sugbọn gbogbo nnkan waye gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fẹ, ni asiko rẹ. Ti asiko ba to , o ti ya niyẹn.

“Rudeboy, ti o ko ba wọ ijọba oorun, pe me ni ẹran. Wa wọ ijọba oorun, a o jọ joko pẹlu awọn angẹli, ti a si jọ jẹun papọ.

“Nnkan ti awọn eeyan yo sọ nipa oni ni pe bawo lo ṣe jẹ? Sugbọn Mr Ibu ati P-Square ko ki n ṣe ọmọ iya kana.”

Rudeboy lo gbe fọnran naa sori ayelujara Instagram rẹ, to si ni sapejuwe fọnran ọhun gẹgẹ bi eyi to ba lọkan jẹ pupọ.

Saaju ni Paul Okoye ti kọkọ gbe sori ayelujara pe oun lo ọpọlọpọ ọsẹ lati sun ni ile iwosan pẹlu Mr Ibu sugbọn ibanujẹ lo jẹ pe iku si waye.

“Mo sun pẹlu Mr Ibu fun ọpọlọpọ ọsẹ lati ri pe alaafia waye sugbọn o pada fi wa silẹ.

Aarẹ ẹgbẹ oṣere Actors Guild of Nigeria, Emeka Rollas ni Mr Ibu ti wa lori aisan fun ọdun mẹrinlelogun.

John Okafor jade laye ni ẹni ọdun mejilelọjọta nmi ile iwosan kan nipinlẹ Eko

Oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni mọlẹbi gbajugbaja oṣere tiata lorilẹede Naijiria, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr Ibu kede pe oṣere naa ti padanu ẹsẹ rẹ kan lori igbiyanju wọn lati mu nwa layẹ.

Mr Ibu wa nile iwosan fun ọpọlọpọ ọjọ, ti awọn ọmọ Naijiria si dawo jọ fun lati fi tọju ara rẹ.

Ninu atẹjade ti mọlẹbi fi soju opo ayẹlujara Mr Ibu, salaye pe Mr Ibu ti ṣe isẹ abẹ meje sugbọn lati ri pe o wa laaye, wọn ni lati ge ọkan lara ẹsẹ rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post