Nàìjíríà wà nínú òkùnkùn, báńkì kọ̀, kò ṣiṣẹ́, iléẹ̀kọ́ wà ní títìpa, wo ọṣẹ́ tí ìyànṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà, NLC ṣe fáráàlú

Ileeṣẹ amunawa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ri ipese ina mọnamọna ni Naijiria, TCN, ti kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lo wa nidii bi ko ṣe si ina jakejado Naijiria.

Ajọ TCN sọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Ndidi Mbah, fi sita ni owurọ ọjọ Aje pe, ni nnkan bi aago kan kọja l’oru mọju , ni ẹgbẹ NLC yabo ibudo ipese ina to wa niluu Benin, ti wọn si fi ipa le gbogbo awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ jade.

“Awọn oṣiṣẹ to kọ lati jade, ni wọn lu, ti awọn miran si farapa lasiko naa.”

Ọgbẹni Mbah sọ pe yatọ si ileeṣẹ amunawa ni Benin, wọn tun ti eyi to wa ni Ganmo, Ayede, Olorunsogo, Akangba ati Osogbo.

Igbesẹ naa ni wọn tun lo kan ibudo ti wọn ti n pese ina to wa ni Jebba, ati awọn miran.

“Fifi agidi pa awọn irinṣẹ lo fa a ti oju opo ina fi dẹnukọlẹ jakejado Naijriia ni nnkan bi aago meji kọja l’oru.”

Ajọ TCN sọ pe oun gbiyanju lati bẹrẹ iṣẹ atunṣe ni Shiroro ati Katampe, ni nnkan bi aago mẹta kọja, ṣugbọn niṣe ni ẹgbẹ oṣiṣẹ n dina mọ wọn.

Wo àwọn iléeṣẹ́ tí kò tẹ̀le ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ kéde
Aworan patako ileewosan kan 'l'Abuja

Bo tilẹ jẹ pe kaakiri orilẹ-ede Naijiria lo ti yẹ ki iyanṣẹlodi alai ni gbedeke ti maa waye bayii bi ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe kede, sibẹ, ko ri bẹẹ lawọn ibi kan.

Akọroyin BBC Yoruba lati ilu Abuja, jabọ pe awọn ileefowopamọ kan n ṣiṣẹ laaarọ ọjọ Aje ti iyanṣẹlodi n lọ kaakiri Naijiria.

Loootọ ni awọn banki naa ko ṣilẹkun wọn silẹ gbayawu, ṣugbọn wọn n jẹ ki awọn onibaara wọle, wọn si n da wọn lohun.

Agbegbe Wuse 2, niluu Abuja ni ọrọ ti ri bayii gẹgẹ bi iwadii akọroyin wa.

Bakan naa ni awọn ileewosan ijọba apapọ ati ti ipinlẹ pẹlu ko darapọ mọ iyanṣẹlodi yii l’Abuja.

Paapaa julọ, awọn eyi to wa ni Maitama. Niṣe ni wọn n da awọn aláìsàn lóhùn ni pẹrẹwu.

BBC Yoruba yoo maa mu iroyin wa fun yin si i nipa iyanṣẹlodi naa bo ba ṣe n lọ.

Nǹkan dẹnu kọlẹ̀ ní báńkì, ilé ẹ̀kọ́, àti iléèṣẹ́ ìjọba nítorí ìyanṣẹ́lódì NLC, TUC

Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Osun

Ẹgbẹ oṣiṣẹ jakejado Naijiria ti bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbede.

Owurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 ni iyanṣẹlodi naa bẹrẹ.

Awọn akọroyin BBC to lọ kaakiri awọn ipinlẹ bii Ogun, Osun, Oyo, Ekiti, Kwara ati Ondo jabọ pe titi pa ni awọn ileeṣẹ ijọba, to fi mọ awọn banki wa.

Bakan naa ni nnkan ṣe ri ni ilu Abuja.

Yatọ si ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba, ẹgbẹ awọn akọroyin (NUJ), àwọn banki, ati awọn ẹka ọrọ aje mii lo tun ti darapọ mọ iyanṣẹlodi ọhun.

Aworan ìwọde ẹgbẹ osisẹ Labour

Ohunkohun kò le yẹ ìpinnu wa lórí ìyanṣẹ́lódì- Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni orilẹ-ede Naijiria, NLC, yari kanlẹ pe oun ko nii yi ero oun pada lori iyanṣẹlodi alainigbedeke to fẹ ẹ bẹrẹ.

Iyanṣẹlodi naa ni wọn ni yoo waye nitori bi ijọba ṣe kuna lati san owo oṣu tuntun ti wọn n beere fun.

Awọn adari ẹgbẹ naa, Joe Ajaero to jẹ aarẹ ẹgbẹ NLC, ati akẹẹgbẹ rẹ, Festus Osifo, to jẹ ti TUC, sọ fun awọn akọroyin ni alẹ ọjọ Aiku pe, iyanṣẹlodi naa yoo waye.

Wọn sọ eyi lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu olori ile igbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio ati ti ile igbimọ aṣofin kekere, Tajudeen Abbas niluu Abuja.

Ipade naa to waye niluu Abuja, lo gbe wọn to wakati mẹrin, nibi ti awọn aṣofin naa ti gbiyanju lati pẹtu si ọkan awọn oṣiṣẹ naa pe ki wọn ma ṣe lọ fun iyanṣẹlodi.

Osifo sọ fun awọn akọroyin lẹyin ipade naa pe"ni asiko yii, a ko ni agbara lati ni ki iyanṣẹlodi maa waye lọjọ Aje, iyanṣẹlodi yoo waye ti a o si gbe ọrọ ti ile igbimọ aṣofin ba wa sọ lọ ijiroro pẹlu awọn eeyan wa,"

Titi pa ni awọn banki ti awọn akọroyin BBC ṣe abẹwo si niluu Akure, Abeokuta, ati awọn ibomii wa
Àkọlé àwòrán, Titi pa ni awọn banki ti awọn akọroyin BBC ṣe abẹwo si niluu Akure, Abeokuta, ati awọn ibomii wa
Awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ko yọju si ibi iṣẹ nitori iyanṣẹlodi naa
Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ko yọju si ibi iṣẹ nitori iyanṣẹlodi naa
Iyanṣẹlodi ọhun ko yọ awọn ile ẹkọ to jẹ ti ijọba silẹ
Àkọlé àwòrán, Iyanṣẹlodi ọhun ko yọ awọn ile ẹkọ to jẹ ti ijọba silẹ

Ile igbimọ aṣofin ni ipade naa da lori bi iyanṣẹlodi naa ko se ni ṣe akoba nla fun eto ọrọ aje orilẹede Naijiria.

Alaga ile igbimọ aṣofin mejeeji lori ọrọ osisẹ, Diket Plang ati Adegboyega Adefarati naa wa nibi ipade naa.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn olori ẹgbẹ oṣisẹ sọ, wọn gbe igbesẹ iyanṣẹlodi nitori gbedeke ọjọ ti wọn fun ijọba apapọ lati wa ojutuu si ọrọ owo oṣu to kereju ti dopin.

Ẹgbẹ oṣisẹ tun binu jade ninu ipade pẹlu ijọba apapọ lọjọ Ẹti, ti wọn si kọ N60,000 ti ijọba gbe kalẹ lati san.

Igba mẹrin ni ijọba ti daba owo oṣu to le san - akọkọ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta Naira ti wọn kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta Naira ti wọn mẹnuba lọjọ Iṣẹgun, nigba ti ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira jẹ igba kẹta, ko to tun wa kan ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ti wọn kọ lati tẹwọgba