Ọkùnrin tó ta ọmọ ara rẹ̀ ní ₦1.5m dèrò àgọ́ ọlọ́pàá

Handcuffs

Oríṣun àwòrán, Meta AI

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti tẹ ọkunrin kan lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o gbiyanju lati ta ọmọ rẹ obinrin ni miliọnu kan abọ naira.

Afurasi naa, ti orukọ rẹ n jẹ Yusuf Umar, jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta, o si pe ara rẹ ni oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba ibilẹ Warji.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, Auwal Mohammed lo fidi iroyin naa mulẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, Umar ti ṣetan lati fa ọmọ naa le ẹnikan lọwọ ṣugbọn ko mọ pe onibara naa jẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii ikọkọ.

Atẹjade olọpaa sọ pe afurasi naa gbe ọmọ kekere ọhun, to jẹ ọmọ odun marun un kuro lakata iya rẹ ni ijọba ibilẹ Warji to si sọ fun obinrin naa pe oun fẹ gbe lọ ki ẹgbọn oun kan niluu Bauchi.

Ọlọpaa ni “Iya ọmọ naa ko mọ pe afurasi ti gbimọ pọ lati gbe ọmọ ọhun fun ẹnikan ṣugbọn afurasi ko mọ pe ọlọpaa ni ẹni to fẹ gbe ọmọ ọhun fun.”

O fi kun pe ile itura kan ni ọwọ ofin ti tẹ ọkunrin naa niluu Bauchi.

Ninu iroyin miran, ọlọpaa ipinlẹ Bauchi yii kan naa ti fi ṣikun ofin mu awọn ọlọdẹ ibilẹ kan fun ẹsun ipaniyan.

Wọn ni awọn ọlọdẹ ibilẹ naa fiya jẹ ọkunrin kan, Jacob Ayuiba, titi ti ẹmi fi bọ lẹnu rẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o ji N150,000.