Ìwà ìdìtẹ̀ mọ́ ìlú ni àwọn tó ń fipá mú àwọn èèyàn láti jókòó sílé ń hù- Ààrẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, The Presidency
Aarẹ Naijiriia, Bọla Tinubu, ti sọ ọ di mimọ pe iwa iditẹ mọ orilẹ-ede ẹni ni awọn ẹgbẹ IPOB to n fipa mu awọn eeyan lati jokoo sile n hu.
Aarẹ sọrọ yii ninu atẹjade to fi kẹdun iku awọn ṣọja marun-un to waye lasiko ti ẹgbẹ IPOB pete ikọlu ni Ila-Oorun orilẹ-ede yii.
Tẹ o ba gbagbe, awọn ṣọja naa n lọọ pẹtu si aawọ niluu Aba, nipinlẹ Abia ni, l’Ọjọbọ to kọja yii, ki wọn too bọ sọwọ IPOB, ẹgbẹ to n pe fun ominira ẹya Igbo.
Ẹgbẹ to lodi si ijọba Naijiria ni IPOB, o si n fipa mu awọn eeyan Ila-Oorun Naijiria lati ma jade lawọn asiko kan.
Iku awọn ṣọja marun-un yii waye lẹyin oṣu meji ti ologun mẹtadinlogun pade iku ojiji niluu Okuama, ipinlẹ Delta.
Eyi naa jẹ nigba ti wọn n lọọ pẹtu si aawọ laarin ilu meji, ti awọn araalu kan si pa wọn.
Ààrẹ ṣèlérí láti gbógun ti àwọn tó ń pa ṣọ́jà Nàíijíríà láì nídìí
Ninu ọrọ Aarẹ Bọla Tinubu lo ti ṣeleri lati gbe igbesẹ ti yoo gbogun ti awọn ti wọn n pa awọn ṣọja Naijiria lai nidii.
‘’ Awọn ologun ati ọlọpaa lẹtọọ lati da aabo bo wa lọwọ ipayinkeke ati awọn to n da ilu laamu.
‘’Lẹnu iṣẹ wọn ni ọpọlọpọ wọn ti pade iku ojiji, bẹẹ ni awọn ti wọn n da aabo bo tun n foju ọpọlọpọ awọn ologun yii gbole.
‘’ Mo n pe awọn ẹṣọ alaabo gbogbo bayii lati mu awọn to lọwọ ninu ikọlu yii, pẹlu awọn ti wọn n fipa mu awọn eeyan lati jokoo sile.
‘’Iwa ti wọn n hu yii ko lorukọ meji ju iditẹ mọ ilu ẹni lọ’’
Tinubu sọ pe agbara ijọba ka awọn amookunṣeka ti wọn n paayan yii, nitori ila ki i ga ju onire lọ.
Aarẹ ba ẹbi awọn ṣọja to padanu ẹmi kẹdun, bẹẹ lo rọ awọn akẹgbẹ wọn yooku lati ma kaarẹ lẹnu iṣẹ wọn.
Ileeṣẹ ologun paapaa ti koro oju si iku awọn ṣọja marun-un yii, wọn lawọn to ṣiṣẹ laabi naa ko ni i lọ lai jiya.














