Iléeṣẹ́ apínnáká yóò já iná ọọ́físì ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ọmọ ogun l’Abuja nítorí gbèsè

Oríṣun àwòrán, getty images
Awọn alaṣẹ ileeṣe apinnaka ilu Abuja, AEDC, ti kede pe awọn yo ja ina to wọ olu ileeṣe ọlọpaa ati olu ileeṣe ọmọ ogun Naijiria to wa nilu Abuja lẹyin ti wọn jẹ gbese owo ina.
AEDC lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju Facebook ati X rẹ lọjọ Aiku.
Atẹjade naa ni ọjọ Aje, ọjọ kẹta, ọsu Kẹfa yii ni AEDC yo gbe igbesẹ naa ti awọn ileeṣẹ to jẹ gbese naa ba kọ lati san owo ti wọn jẹ.
Lara awọn mii to tun jẹ ileeṣẹ naa lowo ina ni ijọba ipinlẹ Kogi, ijọba ipinlẹ Niger, ileeṣẹ to n ri si irinajo ọkọ ofurufu FAAN, ileeṣẹ eto ẹkọ, ileeṣe to n ri si ọrọ abẹle, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
AEDC ni sisan awọn gbese naa lasiko ṣe pataki lọna ati bojuto awọn irinṣe to fi n pese ina.
O ni “A fẹ kede fun araalu pe ileeṣe AEDC yoo ja ina awọn onibara to jẹ wa lowo lọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.
“Sisan owo yii lasiko to yẹ yoo ran wa lọwọ lati maa ṣe iṣẹ wa bo ṣe yẹ ki si le pese ina fun awọn eeyan.
“A wa fi akoko yii rọ gbogbo awọn to jẹ wa lowo ina ki wọn san awọn owo naa ki asiko ti a fun wọn to pe ki a ma ba ja ina wọn.”

Oríṣun àwòrán, AEDC
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ileeṣẹ apinnaka ni Naijiria yoo kede pe ijọba tabi ileeṣe ijọba Naijiria jẹ oun lowo.
Laipẹ yi ni ileeṣẹ apinnaka ti ẹka ilu Ibadan ja ina to wọ ile iwosan UCH to wa niluu Ibadan lẹyin to ni ile iwosan naa jẹ oun ni owo ti iye rẹ le ni irinwo miliọnu naira (N400m.)
Wayi o, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori atẹjade AEDC naa.
Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu awọn ileeṣe ijọba to jẹ gbese ọhun lawọn mii n bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ naa pe awọn ko ri ina lo bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.












