Ọmọ Naijiria di èrò ilé ẹjọ́ ní UK fún fífi àwòrán ìhòhò àwọn èèyàn lù wọ́n ní jìbìtì

Aworan Afurasi

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọdaran n ta awọn itọsọna lori ayelujara lori bii wọn ṣe le ṣe ma fi ihoho awọn eeyan lu wọn ni jibiti, BBC News ṣe iwadii.

Awọn itọsọna naa fihan bi eeyan ṣe le dibọn bii obinrin lori ayelujara, tan ẹni ti wọn fẹ lu ni jibiti lati fi ihoho rẹ ransẹ, ti wọn yoo lo lati dunkoko mọ.

Lojo Isẹgun ni Olamide Shanu farahan ni ile ẹjọ niluu London. Igbagbọ wa pe o jẹ ọkan lara ikọ ọdaran kan to lu awọn agbalagba ati ọmọde ni jibiti owo toto milọnu meji Pọnhun lotri ayelujara.

Ninu oṣu to kọja, ajọ to n risi iwa ọdaran gbe ikilọ síta fun awọn ile ẹkọ kaakiri United Kingdom, sọrọ nipa ewu lilo aworan ihoho fi lu eeyan ni jibiti.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn amoye sọ pe afikun ti wa fun iye awọn ọmọde ti awọn oniṣẹ ibi n lu ni jibiti, ti iwa ifi ihoho lu wọn ni jibiti si wọpọ ni apa iwọ oorun Afrika, ti pupọ wọn si wa lorilẹede Naijria.

Ni UK, awọn ọdọ meji kan ni wọn gba ẹmi ara wọn ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 lẹyin ti wọn ko si ọwọ eeyan to lu wọn ni jibiti pe wọn ní aworan ihoho wọn lọwọ.

Paul Raffile, oniwadii lori fifi ihoho lu eeyan ni jibiti, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi “idunkoko nla” si awọn ọmọde.

“Awọn eeyan to n lu eeyan ni jibiti lori ayelujara ni ọdun meji sẹyin bayii ti rii pe wọn le di olowo ni kiakia ti wọn ba lu awọn eeyan ni jibiti.

“Paapa awọn ọdọ,” o sọ.

Ọgbẹni Raffile tọka si pe awọn agbalagba lo ti kọkọ ko sọwọ awọn eeyan yii fun ọpọlọpọ ọdun sugbọn bayii awọn ọmọkunrin ni wọn n kọju si lati ṣe ipalara funl.

"Wọn n wa awọn ọmọde yii nipa lilọ lori ayelujar ti wọn si n wa awọn ile-ẹkọ giga ati awọn ẹgbẹ ere idaraya ọdọ, lẹyin nna wọn yoo ba wọn dọrẹ tabi tẹlẹ wọn lori ayelujara," o sọ.

BBC ti rii pe awọn itọsọna lori bi o ṣe le ṣe lu awọn eeyan ni jibiti pẹlu ihoho wa ni gbangba fun tita ni awọn fidio lori ayelujara.

Wo bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa fífi ìhòòhò lú èèyàn ní jìbìtì
Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn ti sapejuwe rẹ ni kunkun pe wọn sẹda ayederu nọmba ti wọn ko le ṣawari pẹlu ayederu eeyan lori ayelujara ati ọna lati pawo wọle.

Diẹ ninu awọn nọmba ti wọn ti lu ni jibiti, ọkan kowe pe eeyan to lu ni jibiti maa sanwo fun u nigbagbogbo, “gbogbo ọjọ Ẹti”.

Ọmọ Lucy, ọmọ ọdun mẹrinla ko sọwọ awọn eeyan to n lu eeyan ni jibiti lọdun yii

Bo ti lẹ jẹ pe ko fi aworan rẹ kankan ranṣẹ, awọn ọdaran yii sẹda aworan ati atẹjisẹ ti wọn si n dunkoko mọ pe yoo pin kiri

“Atẹjisẹ ni, to n sọ pe, 'maṣe pa wa mọ. Ti o ko ba fi owo ranṣẹ si wa ni laarin wakati mẹrinlelogun, a yoo fi aworan ranṣẹ si gbogbo awọn olubasọrọ rẹ, "o sọ.

“O jẹ ohun ijaya, to si bẹrẹ si ni ma bẹru.”

Ọdọmọkunrin naa ti san £100 fun awọn ọdaran yii saaju, ṣugbọn pẹlu iranlọwọ awọn obi rẹ, o sọ foonu rẹ nu tí ko si gbọ mọ lati ọdọ awọn ọdaran onijibiti naa mọ

"Ti ko ba se pe o wa ni owurọ ọjọ yẹn, ati pe emi ko si ni ile idana, ti ko ba ṣe pe o tun ba mi sọrọ, n ko mọ bii yoo jasi fun u,” Lucy sọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn alaṣẹ Amẹrika ti bẹrẹ igbesẹ lati fi ofin gbe Ọgbẹni Shanu, ẹni to ti farahan ni Ile-ẹjọ Majisireti ni Westminster.

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ọhun, ni wọn n wa ni ipinlẹ Idaho lori ẹsun ole jija, kiko owo lọna aitọ ati títọ pinpin eeyan lori ayelujara.

Awọn ẹsun naa ni awọn mẹrin fara kasa ti ọkan ninu wọn jẹ ọmọde.

Awọn oniwadi gbagbọ pe ogunlọgọ awọn eeyan lo fara kasa iwa yii laarin ọdun mẹta.

Ọgbẹni Raffile sọ pe awọn ile-iṣẹ imọ ẹrọ nla ko ṣe to lati da iwa lílo aworan lu eeyan ni jibiti duro.

“Iwa ọdaran yii ti gbilẹ gan an lori Instagram ati Snapchat ni ọdun meji sẹyin…"

Snapchat sọ fun BBC pe: “A ti n gbe awọn igbesẹ lati doju kọ iwa yii, ti a si ti pese bi wọn yoo ṣe kan si wa ti ẹnikẹni ba fẹ fí aworan dunkoko mọ ẹnikẹni.

Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ Meta, to ni Instagram, sọ pe awọn ti pese “aye bi wọn se le fẹ jọ sun ti ẹnikẹni ba dunkoko pe ki awọn eeyan fi aworan ihoho wọn ransẹ ”.

TikTok naa sọ pe awọn ti gbe igbesẹ “a ko faye gba ẹnikẹni lori ikanni lati dunkoko mọ ẹnikẹni tabi faaye gba awọn aworan ihoho."