Àwọn sọ́jà yabo àgọ́ ọlọ́paà ní Kwara, wọ́n fi ipá kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kogi tí ọlọpàá dóòla lọ

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Ijọba ipinlẹ Kogi ti fidi ẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ Confluence University of Science and Technology, mẹjọ to ṣẹku ni igbekun awọn ajinigbe ti gba itusilẹ bayii nipinlẹ Kwara.
Iroyin sọ pe ọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni awọn akẹkọọ yunifasiti to wa ni Osara nipinlẹ Kogi naa gba itusilẹ.
Inu igbo kan nipinlẹ Kwara ni wọn ti ri awọn akẹkọọ ọhun gba lẹyin ajọṣepọ awọn ẹṣọ alaabo ati ijọba ipinlẹ Kwara.
Ọjọ kẹsan-an oṣu Karun-un ọdun 2024 ni awọn ajinigbe yawọ fasiti naa wi wọn si gbe awọn akẹkọọ nibiti wọn ti n kawe.
Amọ ọrọ gba ibomiran yọ nigba ti awọn ọmọ ologun kan yabo agọ ọlọpaa ti wọn ko awọn akẹkọọ ọhun si, ti wọn si fi ipa ko wọn lọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, sọ ninu atẹjade kan pe awọn sọja ọhun yabo agọ ọlọpaa to wa ni Oro-Ago, lasiko ti wọn n ṣeto bi wọn yoo sẹ gbe awọn akẹkọọ naa lọ si ileewosan fun itọju.
“Lasiko ti awọn ọlọpaa n ṣeto gbigbe awọn akẹkọọ naa lọ si ilu Ilorin, ni awọn soja to wa ọkọ ileeṣẹ ologun mẹta, yabo agọ ọlọpaa Oro-Ago, ti wọn si bi ipa gbe awọn akẹkọọ naa, lai jẹ ka ko wọn silẹ lọna to yẹ.
“Igbesẹ naa jẹ iwa afojudi si ileeṣẹ ọlọpaa, ko si ṣe itẹwọgba.”
DSP Ejire-Adeyemi sọ pe awọn yoo gbeigbesẹ to yẹ lori ọrọ naa.
Nnkan bii aago mẹjọ-aabọ alẹ la gbọ pe wọn wọ ọgba ileewe naa ti wọn si ji awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn nigba naa gbe sa lọ.
Lọjọ keji ijinigbe naa ni awọn alaṣẹ fasiti yii kede pe akẹkọọ mẹsan-an ni wọn ji gbe, ki wọn too pada sọ pe mẹrinla ni apapọ awọn ọmọ ti wọn ji gbe sa lọ naa.
Orukọ awọn ọmọ to gba itusilẹ naa ree bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣe gbe e jade: Anate Hanifat Oyiza, Damisa Rasidat Ometere, Ahmed Tijani Fatimah, Obakachi Mashkurah Onyioyiza.
Awọn yooku ni Oloruntoba Blessing Kemisola, Omojo Godwin, Abdulrafiu Abdulmakik Enesi ati Musa Oseni.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Bernard Onuoha, ṣe ṣalaye, o ni meji ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe naa jade laye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun ọdun 2024.












