Ọgbọ̀n ọjọ́ lòfin là kalẹ̀ fún sísan owó oníbárà báǹkì tó bá wọmi, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje la ó fi san tàwọn Heritage Bank - Ọ̀gá àgbà NDIC

Oríṣun àwòrán, CBN/Heritage
Ajọ adojutofo iṣuna lorilẹede Naijiria, NDIC ti fi da awọn onibara banki Heritage Bank loju pe awọn ti bẹrẹ igbaesẹ lori sisan owo awọn onibara banki naa eyi ti banki apapọ Naijiria gbẹsẹ le lọjọ Aje ọsẹ yii.
Oludari agba ajọ NDIC, Bello Hassan lo sọ eyi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, olu ilu Naijiria lọjọru.
O ṣe alakalẹ bi ilana sisan owo naa pada yoo ṣe lọ, o ni láàrín ọ̀sẹ̀ kan làwọn yóò fi yanjú ti àwọn oníbárà Heritage Bank.
O ni, “Iwadii akọkọ fihan pe nnkan bii ẹgbẹta o le aadọta biliọnu Naira lowo awọn onibara to wa ni Banki naa, iye owooya ti banki naa ya sita jẹ ẹẹdẹgbẹrin biliọnu Naira.”
Ni ọjọ Aje ni banki apapọ Naijiria, CBN fa iwe aṣẹ banki Heritage ya nitori aile ṣe ojuṣe rẹ bi o ti yẹ gẹgẹ bii ile ifowopamọsi mọ.

Oríṣun àwòrán, hbng.com
Gẹgẹbi Banki apapọ Naijiria, CBN ṣe sọ, “Awọn igbimọ ati adari banki naa ko lee mu ilọsiwaju ba eto iṣuna rẹ mọ, eyi si jẹ ohun to lewu fun idyrodeede iṣuna rẹ,”.
Adari ajọ adojutofo iṣuna lorilẹede Naijiria, NDIC naa tun ṣalaye siwaju sii pe “miliọnu meje ati ọọdunrun ni awọn Onibara banki ọhun, ida mọkandinlọgọrun un wọn iye owo wọn to wa ni ipamọ banki naa ko to miliọnu marun un naira eleyi to ṣi wa labẹ arọwọto eto idojutofo awọn onibara banki.”
O ni eto ayẹwo n lọ lọwọ bayii fun awọn onibara Banki naa gẹgẹ bi ara igbesẹ lati san awọn owo to bọ sabẹ eto idojutofo ti ko ju miliọnu marun un Naira lọ.
Amọṣa o ni gbogbo awọnb ti owo wọn to wa ni ikawọ banki naa ba ti ju miliọnu marun un Naira lọ yoo ni lati duro de igba ti wọn ba ta awọn dukia banki naa tan ni.

Oríṣun àwòrán, Intel Region
Lẹyin ti iroyin gbode pe banki apapọ Naijiria, CBN, ti gba iwe aṣẹ ti ileeṣẹ ifowopamọ Heritage Bank fi n ṣiṣẹ, ọpọ araalu ti bẹrẹ si n bere ohun ti yoo ṣẹlẹ si owo wọn to wa nile ifowopamọ naa.
Pupọ ninu awọn eeyan ọhun lo n woye asiko ti wọn yoo ri owo wọn gba pada ati igbesẹ lati gba owo naa.
Ibẹru ti gba ọkan awọn onibara ile ifowopamọ Heritage nitori bi banki agba Naijiria CBN ṣe gba iwe asẹ wọn, nipa ọ̀nà ti owo wọn yio gba kuro ni banki naa
CBN tiwa fa isẹ yiyanju ọrọ naa sikawọ ajọ kan to n mojuto ìdójútòfò nipa fifowopamọ ni Naijiria,[NDIC], lọwọ.
Wọn yio bẹrẹ sisan gbèsè ti banki ọhun jẹ awọn onibara rẹ pada, bakan naa, wọn yoo tun gba awọn gbese ti awọn onibaara jẹ banki naa wọle nipase lilo ilana ayẹwo to muna doko.
Kíló máa ṣẹlẹ̀ sí owó àwọn oníìbárà?
Ajọ NDIC sọpe, awọn onibaara to ba ni aṣuwọn owo si banki miran, ni anfaani lati gba to milliọnu marun-un Naira.
Awọn onibaara ile ifowopamọ Heritage to ba ni kọja milliọnu marun-un naira ni won yoo maa sanwo pada fun latara ele wọn lẹyin igba ti wọn ba ti sakojọpọ owo banki naa pẹlu gbigba gbogbo gbese ti awọn eeyan n jẹ banki naa wọle tan.
Nọmba idanimọ banki, [BVN] lajọ naa yoo lo lati ṣawari awọn aṣuwon banki mii ti awọn onibaara ba ni si banki miran.
Eyi yoo ran NDIC lọwọ lati mọ pato iye owo wọn.
Báwo wá ni àwọn oníìbára tí kò ní àṣùwọ̀n míràn yóò ti rí owó wọn padà?
Gbogbo awọn onibaara banki to dẹnukọlẹ ọhun, laini aṣuwọn banki miran gbọdọ yọju si ẹka banki Heritage to ba wa nitosi.
O si gbọdọ mu ẹri dani pe oun gan ni ojulowo ẹni to ni aṣuwọn naa bii iwe asẹ iwakọ, kaadi idibo, kaadi idanimọ ilẹ Naijiria ati nọmba aṣuwọn banki mii ti wọn lee fi owo naa ranṣẹ si.
Lọ sibẹ pẹlu nọmba idanimọ banki [BVN].
Lẹyin afihan awọn ẹri wọnyii, ayẹwo yoo bẹrẹ lori bi won yoo ṣe san owo onibara to ba wa ninu aṣuwọn naa pada fun-un.
Itakun agbaye
Awọn onibaara tun lẹtọ ṣiṣe awawi nipa owo wọn nipasẹ kikan si oju opo ayelujara ajọ NDIC.
Yẹ oju opo naa wo, gba atẹ naa sori ẹrọ rẹ koo si ṣalaye ohun to fẹ sinu fọọmu.
Lẹyin eyi, gba ohun tiwọn fẹ mọ nipa ọrọ naa wọle.
Ajọ NDIC sọ pe lẹyin ti wọn ba ti gba gbogbo gbese tawọn to jẹ banki ọhun lowo wọle tan, isẹ bẹrẹ lori sisan owo pada fun awọn onibaara.
Bakan naa ni oludari ẹka iroyin lajọ naa, Bashir Nuhu sọ pe ki awọn eeyan maa ba idokowo lọ pẹlu banki naa lai bẹru ohunkohun rara.
Àwọn ilé ìfowópamọ́ tó ti pàdánù ìwe àsẹ isẹ wọn ní Naijiria
Afribank Nig Plc
Afribank jẹ ọkan lara awọn ile ifowopamọ to lọjọ julọ ni Naijiria ti wọn lọdun 1959, ko to di ipe banki apapọ naijiria CBN gba agbara lọwọ wọn lọdun 2011 nitori awọn iṣoro olowo-de to sẹlẹ siwọn.
Ṣugbọn ninu atẹjade ti CBN fi lede lọdun 2011 ni wọn ti yọnda dukia tojẹ ti Afribank ọhun sikawọ Mainstreet Bank plc.
Bank PHB Plc
Lati ọdun 2005 ni wọn ti gbe Bank PHB Plc kalẹ, bẹẹ laarin igba kan lo bọ si ipo banki karun-un to n pese owo julọ ni Naijiria.
Amọ, wọn ko koju osunwọn fun awọn ilana tiCBN la kalẹ fun wọn, ninu eto idokowo banki tuntun. Eyi si fa gbigba dukia ọhun kuro lọwọ wọn fun Keystone Bank Plc Limited.
Spring Bank Plc
Springbank Plc jẹ ọkan lara awọn ile ifowopamọ mẹfa kan ti wọn ko papọ soju kan-na, sugbọn lọdun 2011 ni CBN fagile iwe aṣẹ rẹ.
Igba wo ni awọn onibara Heritage Bank yoo ri owo wọn gba pada?
Amọ onimọ nipa eto ọrọ aje kan, Shu'aibu Idriss Mikati, ti sọ fun BBC pe ọna ati ri owo naa gba pada ko le ya bi awọn eeyan ṣe ro pe yoo ri.
O fi kun pe nitori ọpọ igbesẹ ti ọrọ naa yoo la kọja, owo ọhun ko ni jade ni kankan, o si le gba ọpọ ọdun.
Ninu ọrọ rẹ, oniruru awọn eeyan ati ẹka ile ifowopamọ ni ọrọ naa yoo gba kọja ko to di pe ajọ adojutofo awọn ile ifowopamọ, NDIC, yoo to le maa san owo naa fun awọn onibara Heritage Bank.
Amọ o fi kun pe o le to ogun ọdun ki awọn onibara ile ifowopamọ naa to ri owo wọn gba pada.
O ni “Ni ti ibere pe igba wo lawọn onibara Heritage bank le ri owo wọn gba pada, idahun ibere yẹn ṣoro diẹ.
“Nitori ko si ẹni to le sọ akokoko naa, mi o le sọ, koda, CBN ati NDIC funra wọn gan ko le sọ nitori onururu ilana ni wọn maa la kọja ki owo ọhun to jade.
“Ki wọn to le san owo yẹn, o le to ọdun marun un tabi ogun ọdun si asiko yii, ṣe ẹ ranti nnkan to ṣelẹ si ile ifowopamọ Savannah?”
Onimọ nipa ọrọ aje naa ṣalaye siwaju si pe o ṣeeṣe ki awọn to lowo ni Heritage Bank ri owo wọn gba pada amọ kii ṣe ni kankan.
Mikati pari ọrọ rẹ pe oun ni onibara kan to ni owo ti iye rẹ to biliọnu mẹta naira ni Heritage Bank, oun si ti bẹrẹ si n kọminu lori irufẹ ipo ti ọkunrin naa yoo wa bayii lẹyin igbeṣe CBN.
CBN gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ Heritage Bank, wo nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí owó rẹ́ lẹ́yìn ìgbésẹ̀ yìí
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti gba iwe aṣẹ to fun Heritage Bank, lati ma a fi ṣiṣẹ.
Gẹgẹ bi CBN ṣe sọ, banki naa tapa si awọn abala kan ninu ofin to de awọn banki, ti ọdun 2020.
CBN sọ ninu atẹjade to fi si oju opo X rẹ pe awọn oludari ati igbimọ oluṣakoso banki naa kuna lati mu ki banki naa ṣe daadaa , eyi to n dunkooko mọ iduroṣinṣin rẹ.
“Leralera ni banki naa n ṣubu, ti ko si ni ireti kankan pe yoo pada dide ja oju ọna to yẹ. Eyi si lo fa a ti gbigba iwe aṣẹ lọwọ rẹ ṣe jẹ igbesẹ to jẹ dandan.”
Ohun ti eyi tumọ si ni pe ko si nnkan to n jẹ Heritage Bank mọ. CBN si ti fa iṣẹ le ajọ to n mojuto eto adojutofo fun awọn banki, Nigeria Deposit Insurance Corporation (NDIC), lọwọ lati ta banki naa ni ibamu pẹlu ofin.
Ọdun 1970 ni Heritage Bank bẹrẹ, pẹlu orukọ Societe Generale Bank (Nigeria).
Oloogbe Olusola Saraki si lo da a silẹ.
Awọn ẹsẹ ti Heritage Bank ṣẹ
Gẹgẹ bi abala keji ofin to de awọn banki ṣe sọ, Gomina CBN ni agbara lati gba iwe aṣẹ banki pada, pẹlu aṣẹ lati ọwọ igbimọ oludari rẹ.
Lara awọn nnkan to si le mu ki iru igbesẹ naa waye ni:
Ti banki ba dẹkun lati ma a sẹ iru eto ifowopamọ ti wọn fun ni iwe aṣẹ fun, fun bi oṣe mẹfa
Ti banki ko ba ri owo ṣe owo mọ, tabi to kogba wọle
Ti banki ko ba le pa awọn ilana to mu ki wọn o fun ni iwe aṣẹ, mọ
Ti banki ko ba ni dukia to to lati ma a ṣiṣẹ
Ti banki ba ṣe awọn okoowo to jẹ jibiti, tabi ti awọn oludari rẹ ba ṣe nnkan ti ko yẹ
Igba akọkọ kọ niyii ti CBN gba iwe aṣẹ banki naa
Igba keji re e ti banki apapọ, CBN, gba iwe aṣẹ lọwọ Heritage Bank.
Lọdun 2006, nigba ti Chukwuma Soludo fi jẹ gomina CBN, o gba iwe aṣẹ lọwọ Societe Generale Bank, lasiko ti atunto waye.
Nigba naa, soludo sọ owo ti banki kọọkan gbọdọ ni fun idokowo di biliọnu marundinlọgbọn sipo biliọnu meji Naira.
Igbesẹ naa din awọn banki ku si mẹrinlelogun lati mọkandinlaadọrun.
Lọdun 2023, Societe Generale Bank tun pada bẹrẹ iṣẹ pẹlu orukọ tuntun, Heritage Bank.
Ṣugbọn iwe aṣẹ ti CBN fun wọn fi ofin de wọn pe wọn ko el ṣiṣẹ tayọ ẹkun kan ni Naijiria.












