Opay, Kuda, gbe ìlànà tuntun kalẹ̀ fún àwọn oníbàárà lẹ́yìn tí CBN gbẹ́sẹ̀ lórí òfin tó fi dè wọ́n

Àwòrán àsíá Opay àti Kuda

Oríṣun àwòrán, Opay/Kuda/X

Ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára, Opay àti Kuda ti ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àwọn oníbàárà tuntun padà lẹ́yìn tí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ti fún àwọn láṣẹ láti máa gba oníbàárà tuntun.

Orí ayélujára X ni Opay àti Kuda tí ṣe ìkéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àwọn oníbàárà tuntun lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà, ọdún 2024.

Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kẹrin ọdún 2024 ni CBN fòfin de àwọn ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára náà pé wọn kò gbọdọ̀ gba àwọn oníbàárà tuntun mọ́ fún ìgbà kan ná.

CBN ní nítorí ìwádìí kan tí àwọn ń ṣe lórí ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ àti láti ri pé àwọn èèyàn kò máa lo àwọn ilé ìfowópamọ́ náà láti ṣe ìwà àìtọ́ ni àwọn fi gbé ìgbésẹ̀ náà.

Lẹ́yìn náà ni CBN gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ fún àwọn iléeṣẹ́ náà láti ṣe àmúṣẹ rẹ̀ kó tó di ogúnjọ́ oṣù Karùn-ún ọdún 2024.

Lára àwọn ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀ náà ni pé wọn kò gbọdọ̀ fàyè gba fífi crypto ránṣẹ́ lórí ìkànnì wọn.

Bákan náà ni wọ́n gbọ́dọ̀ gba àdírẹ́sì ilé àwọn oníbàárà wọn kalẹ̀, kí wọ́n sì ní àwòrán ojú wọn lọ́wọ́.

Nígbà tó ń kéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba oníbàárà tuntun, Opay tẹmpẹlẹmọ pé àwọn ní ìfarajìn sí títẹ̀lé àwọn ìlànà tí CBN gbé kalẹ̀ fún wọn.

“Inú wa dùn láti kéde pé CBN ti fàyè gba Opay láti máa gba oníbàárà tuntun. Èyí ṣàfihàn ìfarajìn wá sí títẹ̀lé òfin àti ìlànà tó yẹ láti ri pé a dá ààbò bo àwọn oníbàárà wa.”

Kuda náà ní tirẹ̀ ní láti bíi ọjọ́ mélòó kan ni àwọn ti ń bá CBN ṣe ìpàdé láti ri pé àwọn tẹ̀lé àwọn ìlànà tí wọ́n fi léde lórí akoto owó àwọn oníbàárà.

Iléeṣẹ́ náà ní pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àti ìgbésẹ̀ tí àwọn ṣe ló so èso rere àti pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba oníbàárà tuntun padà.

Àtẹ̀jáde tí Opay fi léde

Oríṣun àwòrán, Opay/X

Àwọn ìlànà tí oníbàárà gbọ́dọ̀ tẹ̀lé láti ṣí apò àsùnwọ̀n owó tuntun

Kuda ní kí ẹnikẹ́ni tó lè ṣí akoto owó ipele kẹta pẹ̀lú àwọn, oníbàárà náà gbọ́dọ̀ pèsè àwọn nǹkankan.

Àwọn nǹkan náà nìwọ̀nyí:

  • Oníbàárà gbọ́dọ̀ pèsè nọ́ḿbà ìdánimọ̀ NIN rẹ̀
  • Oníbàárà gbọ́dọ̀ pèsè nọ́ḿbà ìdánimọ̀ ilé ìfowópamọ́ báǹkì rẹ̀ ìyẹn BVN
  • Oníbàárà gbọ́dọ̀ pèsè ẹ̀rí àdírẹ́sì ibi tí ó ń gbé tí àwọn yóò sì ṣe ìwádìí láti fìdí ibẹ̀ múlẹ̀
Àtẹ̀jáde tí Kuda fi léde

Oríṣun àwòrán, Kuda/X