Ṣé lóòtọ́ ni obìnrin kan fi ọmọ odó fọ́ orí ọkọ rẹ̀ l’Ondo nítorí pé ó yànlè?

Oríṣun àwòrán, Others
Latari iroyin kan to n ja ran-in lori ayelujara nipa obinrin kan, Omolara Jamiu ti wọn ni o la ọmọ-ori-odo mọ ọkọ rẹ lori nitori ale nipinlẹ Ondo, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe awọn ko le sọ pe oun lo pa a.
Ṣe ohun to gba ẹnu ọpọ eeyan niluu Akungba Akoko ti iṣẹlẹ naa ti waye ni pe Omọlara la ọmọ-ori-odo mọ Seidu Jamiu, ọkọ rẹ lori lasiko ti ọkunrin naa n sun lopin ọsẹ to kọja.
Iroyin sọ pe ija ti kọkọ waye laarin Ọmọlara ati ọkọ rẹ lori ọrọ ọmọbinrin kan ti a gbọ pe Oloogbe Seidu n yan lale.
Ija naa ni wọn ni ko tan ninu iyawo to fi la ọmọ-ori-odo mọ ọkọ rẹ lori lasiko to n sun.
Bo tilẹ jẹ pe wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sile iwosan lẹyin ti iyawo rẹ kigbe pe ki awọn ara adugbo gba oun, sibẹ, iku lo pada ja si fun Seidu.
Ohun ti awọn ara adugbo sọ ni pe Ọmọlara lo pa ọkọ rẹ.
Wọn ni nigba to ri i pe o ti ku lo sare gba agọọlọpaa lọ lati sọ ohun ti ko ṣẹlẹ.
Àlàyé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ibukun Ọdunlami ṣalaye pe awọn ko le fidi ẹ mulẹ pe Ọmọlara lo pa ọkọ rẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, Ọdunlami sọ pe "Loootọ la gbọ pe ọkunrin naa ku, ati pe ẹsun ipaniyan wa nilẹ, ṣugbọn a ko le fidi ẹ mulẹ pe iyawo rẹ lo pa a.
"A ti taari ẹjọ naa lọ si ẹka CID to n tọpinpin iwa ọdaran nipinlẹ Ondo’’
Iwadii kikun ati itọpinpin lo le fidi ohun to fa iku oloogbe mulẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi.
Wọn ni iyawo ti wọn n fẹsun kan yii lo waa fi iku ọkọ rẹ to awọn leti.
Olufisun ni awọn ọlọpaa pe Ọmọlara lasiko yii, afi ti iwadii ba sọ nnkan mi-in lo ku.














