Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára Cervical Cancer tí ìjọba Naijiria n pín fún àwọn ọmọbìnrin

Oríṣun àwòrán, Getty Image
Ọkan ninu awọn arun aṣekupani to ti da ẹmi ọpọ eeyan legbodo ni arun Jẹjẹrẹ ti a mọ si Cancer.
Bo tilẹ jẹ pe awọn dokita sọ pe Jẹjẹrẹ gbọ oogun beeyan ba tete mọ to si fun un nitọju to yẹ, sibẹ, ilana to daa ju lati koju arun naa ni didena rẹ nipa gbigba abẹrẹ ajẹsara.
Ti a ba yọwọ Jẹjẹrẹ ọyan to n pa awọn obinrin, ikeji to tun da bii rẹ ni eyi ti a mọ si Cervical Cancer, to maa n yọ ẹnu ile ọmọ obinrin lẹnu.
Jẹjẹrẹ yii naa maa n pa awọn obinrin pupọ, ṣugbọn pẹlu abẹrẹ ajẹsara ‘Human Papillomavirus (HPV) yii, idena jẹjẹrẹ ṣee ṣe.
Ijọba apapọ Naijiria ti kọkọ kede pe abẹrẹ ajẹsara HPV yii yoo wa loṣu kẹwaa ọdun 2023. Paapaa fun awọn ọdọmọbinrin ti wọn ko ti i bẹrẹ si i ni ibalopọ.
Awọn ọmọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ju mẹsan-an si mẹrinla lọ.
Eyi ni wọn ni yoo dena arun jẹjẹrẹ oju ara fun wọn, awọn ileewe alakọọbẹrẹ ati ti girama kan si jẹ anfaani naa lasiko ọhun.
Kí gan-an ni HPV?
HPV jẹ kokoro kan to le mu eeyan nibikibi ninu ara.
O le mu eeyan loju ara, inu ile ọmọ obinrin, isalẹ nnkan ọmọkunrin mejeeji ati oju ibi ti igbọnsẹ ti n jade paapaa.
Ṣugbọn awọn kokoro HPV to n mu eeyan loju ara yii maa n waye lati ara ibalopọ ni lọpọ igba.
Awọn kan wa ti wọn le mu eeyan lati ara fifi ara ro ẹni to ba mu.Iru eyi ko nilo ibalopọ ko too ṣẹlẹ si eeyan.
Awọn kokro HPV kan maa n mu eeyan loju ara ti wọn ko lewu rara, bẹẹ lawọn kan wa ti wọn lewu pupọ.
HPV to ni ewu yii le yi pada ko di Jẹjẹrẹ oju ara ta a mọ si Cervical cancer.
Ṣugbọn beeyan ba tete dena rẹ, ko ni i la ewu lọ.
Àpẹẹrẹ wo lèèyan yọò fi mọ̀ pé òun ti kó HPV?
Kokoro HPV to n ba oju ara ja ki i sabaa mu apẹẹrẹ kankan dani, ohun to le farahan ko ju bii kókó kekere ti yoo kan le si abẹ eeyan lọ.
Ṣugbọn ki i ṣe gbogbo kókó to ba yọ si oju ara eeyan ni apẹẹrẹ HPV o.
Awọn kan wa to jẹ won ko lewu rara bi awọn dokita ṣe wi, ti wọn yoo si tun parẹ funra wọn.
HPV le foju han lẹyin ọsẹ, oṣu abi ọdun paapaa lẹyin igba teeyan ba ti ko arun naa.
Fun awọn HPV to ni i ṣe pẹlu ibalopọ, wọn le ran ẹni ti ko ni i tẹlẹ nigba to ba ni ibalopọ pẹlu ẹni to ni HPV.
HPV to lewu yii ki i sabaa foju han afi ti wọn ba ti di Jẹjẹrẹ tan.
Bi ayẹwo ba fidi ẹ mulẹ pe eeyan ti ni kokoro HPV, ko tumọ si pe ẹni naa ti ni Jẹjẹrẹ niyẹn.
Báwo lo ṣe lè kó kòkòrò HPV?
Nini ibalopọ pẹlu ẹni to ni kokoro HPV, omi ara bii àágùn, fifi ahọn la oju ara ẹni ti kokoro yii ti mu, nini ibalopọ onifurọ (anal sex)
HPV ki i ṣe fun obinrin nikan, o le mu ọkunrin naa nigba to ba ko o lati ara ẹni yoowu to ba mu.
Gẹgẹ ba a ṣe ṣalaye ṣiwaju, kokoro HPV le di jẹjẹrẹ ile ọmọ lara obinrin bi eeyan ko ba tete tọju rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Image
Àyẹ̀wò àti ìtọ́jú HPV
Fun obinrin, ayẹwo ti oloyinbo n pe ni Pap smear, eyi ti wọn maa n ṣe loju ara, le fi han beeyan ba ti ni HPV tabi bẹẹ kọ.
Ayẹwo HPV funra rẹ naa si wa.
Omiran wa ti wọn n pe ni Colposcopy. Eyi maa n waye lẹyin ti ayẹwo Pap smear ba ṣafihan awọn apẹẹrẹ ti ko yẹ.
Bawo lo ṣe le dena nini HPV?
Akọkọ ni yiyago fun ibalopọ, gbigba abẹrẹ ajẹsara HPV, nini ibalopọ lọna to tọ ati pẹlu ẹnikan ṣoṣo ti ko ni HPV.
Ṣiṣe ayẹwo loore-koore, dida aabo bo ẹni ti ẹ jọ n ṣere ifẹ nipa sissọ fun un ti o ba ni kokoro naa.
Ki o si yago fun ibalopọ lasiko ti o ba n gba itọju lọwọ.
Èrò aráàlu ṣọtọọtọ lórí abẹ́rẹ́ HPV tíjọba Nàìjíríà gbé dé
Bi abẹrẹ ajẹsara to n dena arun rọpa-rọsẹ fawọn ọmọde ṣe wa, ti eyi to n gbogun ti igbona, ibaa pọnju-pọntọ ati bẹẹ bẹẹ lọ wa naa ni HPV tijọba Naijiria ṣẹṣẹ gbe de yii wa fun aisan jẹjẹrẹ ẹnu ile ọmọ.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe awọn eeyan kan ki i fẹẹ gba a.
Igbagbọ awọn eeyan wọnyi ni pe abẹrẹ ajẹsara naa jẹ ọna kan lati din eeyan to wa laye ku.
Awọn mi-in gbagbọ pe abẹrẹ naa yoo maa pa awọn saye diẹdiẹ ni.
Wọn ni nigba to ba si ya, iku yoo de lojiji latari abẹrẹ naa.
Bakan naa lawọn kan sọ pe abẹrẹ HPV yii ko ni i jẹ ki awọn ọmọbinrin awọn ri ọmọ bi lọjọ iwaju.
Awọn mi-in si sọ pe ẹsin ko gba awọn laye, wọn lo lodi si ẹkọ ijọ awọn.
Bakan naa la si ri awọn araalu ti wọn tẹwọgba abẹrẹ naa ti wọn si ṣetan lati gba a fun awọn ọmọ wọn obinrin.
‘Abẹ́rẹ̀ àjesára HPV kò bá ewu dé, àlááfìa ni’'
Lati tan imọlẹ si awọn ero wọnyi, BBC Yoruba ba Dokita Dupe Shittu lati ’Kwara State Primary Helath Care Development Agency’, sọrọ. Eyi ni alaye rẹ.
’’Kokoro to maa n fa arun jẹjẹrẹ lara obinrin ati ọkunrin ni. Jẹjẹrẹ to maa n fa lara obinrin ni ti ẹnu ile ọmọ.
‘’Lati ibi ibalopọ lati maa n ko kokoro yii.
Awọn ẹni to ba n ni ibalopọ pẹlu awọn eeyan to pọ, ti ki i ṣe ẹnikan ṣoṣo lo n ba wọn lo pọ ni wọn maa n ni i.
‘’Awọn ọmọbinrin ti wọn tete bẹrẹ si i ni ibalopọ pẹlu ọkunrin naa wa ninu ewu ati ni arun jẹjẹrẹ yii.
Awọn ti wọn ba n mu siga naa le ni i.
‘’Ṣugbọn abẹrẹ ajẹsara HPV yii jẹ ọna abayọ ti eeyan ko fi ni i lugbadi ẹ.
‘’Koda teeyan ba ti lugbadi arun yii paapaa, abẹrẹ ajẹsara HPV yoo fun awọn ṣọja ara rẹ lagbara lati koju arun naa.
‘’ Eyi ni a n pe ni immunity. Ọna ti a ko fi ni i lugbadi ẹ ni abẹrẹ ajẹsara tijọba gbe jade yii jẹ.
Gbogbo awọn ti wọn n sọ pe wọn fẹẹ fi pa aye rẹ ni, ahesọ ọrọ lasan ni.
Ko sohun to jọ bẹẹ.
Abẹrẹ HPV ko ni i kọmọ ma bimọ lọjọ iwaju, a fẹẹ fi dena arun Jẹjẹrẹ ni. Ko ba ewu de o, abẹrẹ alaafia ni.’’
Ọfẹ́ ni abẹ́rẹ́ HPV fún àwọn ọmọbìnrin, àwọn àgbàlagbà ni yóò ra tiwọn
Nigba to n tẹsiwaju, Dokita Shittu sọ pe ọfẹ ni abẹrẹ ajẹsara HPV fun awọn ọmọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ju mẹsan-an si mẹrinla lọ.
O ni abẹrẹ naa yoo wa ni awọn ileewosan kereje ta a mọ si ‘Primary Health Care Centre’ kaakiri.
Dokita Shittu sọ pe bi abẹrẹ HPV ṣe jẹ ọfẹ fawọn ọmọde, ko ri bẹẹ fun awọn obinrin ti wọn ti dagba.
O ni awọn agbalagba obinrin to ba nifẹẹ si i yoo kọkọ ṣayẹwo lati mọ boya wọn ti ni kokoro naa tabi wọn ko ni.
Bi wọn yoo ba wa gba abẹrẹ HPV, o ni wọn yoo ra a ni.
Eyi le to ẹgbẹrun lọna ọgọta (60,000) bo ṣe wi.
HPV ti wa tipẹ, awọn eeyan ti wọn mọ nipa rẹ maa n ra a fun awọn ọmọ wọn obinrin ni kijọba too sọ ọ di ọfẹ bayii.
Ko si din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin (80,000) nigba naa bi akọsilẹ ṣe sọ.












