Níbo ni Olorì Crypto tó dàwátì wà: Ṣé ó kú ni tàbí ó wà láàyè?

Ruja Ignatova

Ní osù kẹ̀sán-an ọdun 2019 ni ilé isẹ́ BBC bẹrẹ síní se ìwaàdí nípa ìtàn arábìnrin kan, Ruja Ignatova ọ́mọ́ ilẹ́ Bulgaria.

Ignatova di ẹni tí wọ́n ń wá lẹ́yìn tó gbá àwọn éèyàn níye owó tó tó biliọ̀nu mẹ́rin àbọ̀ Dọla nípasẹ̀ lílo apo ìkówópamọ́sí tilẹ̀ òkèèrè rẹ́ eyi tó jẹ́ ayédèrú, kó tó diípé ó júbà ehoro nígbà naa.

Nibáyí a ti ń tọpasẹ̀ re láti mọ̀ pàtó ibi gan tọ́rọ̀ rẹ̀ de dúró, ikọ̀ olùsèwáàdí BBC ti sàwárí íbásepọ̀ rẹ̀ pẹlu ọ̀gá àgbà níléeisẹ́ oníwà ọ̀daràn kan nílẹ̀ Bulgaria, a sì gbọ́ wípé wọ́n ti dẹ́mìí obìnrin náà légbodò.

Njẹ́ omidan Ignatova jẹ̀gbádùn ara rẹ̀ pẹ̀lu ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ bíliọ́nù owó tó jí kó tabí àwọn tíwón sanwó ẹ̀mí rẹ̀ fún paá láti dáàbò bòó ni?

Akéèkọ́ jáde yunifásitì Oxford ni Ruja Iganatova jé, ọmọ bíbí ilẹ̀ Bulgaria ni, ibẹ̀ lósì dàgbà sì kó tó dipé ó bẹ̀rẹ̀ síní sàmúló òpó íkòwópamọ́ ìlà ti OneCoin lọ́dún 2014.

Nípasẹ̀ èyí ló fi gba ọpọ èèyàn káàrkiri àgbáyé níyànjú wípé kíwọ́n wá dòwòpọ̀ pẹ̀lú ìlà ti OneCoin pẹ̀lú ìlérí èrè gọbọi fúnwọn.

Sùgbọ́n ní ótító, arábìnrin Ignatova tọ́pọ̀ mọ̀ sí Dr Ruja ti dọ́gbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti máà gbá àwọn eeyàn láìní akọ̀sílẹ̀ ojúlówó bíi ti ilé isẹ́ Bitcoin.

Ní kété tí àwọn onísẹ́ ìwáàdí ilè Germany àti US pajú isẹ́ wọn dé lórí ọ̀rọ̀ omidan Iganova lósú kẹ́ẹ̀wá odún 2017,ni iròyìn fi léde pé ó lọ gun bàálù tó gbéè kùró ní Sofia lọsí Athens, kíwón ma leè ríi mọ́.

Látọdún diẹ sẹ́yìn ni awọ̀n onísẹ iwáàdí BBC ti n gbìyànjú lati túbò mọ sii nípa rẹ̀ àti ohun tó sẹlẹ si i bóyá ó ṣì wà láyé titi di àsìkò yí.

Ìdí èyí ni láti fi sedamọ eni tí abesínkáwọ̀ rẹ̀ jẹ́.

Richard Reinhardt
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Richard Reinhardt tó bẹ̀rẹ̀ ise iwàádí nípa onecoin fún àjọ tó ń pawó lábẹ́nú nílẹ US sàlàyé fún BBC wípé kòsí nínú àwọn onísẹ́ iwaàdí naa to tii forúkọ̀ rẹ̀ léde ní gbangba ri.

Bákànà lósì yéwa pé okùnrin kan niwọ́n gbé isẹ́ àábo omidan Ignatova fún, orukọ ni Hristoforos Nikos Amanatidis tọ́pọ̀ mọ̀sí Taki.

Àti wípé okùnrin olóògùn olóró kan ló ń ṣe ojúse dídàábò bo arábìnrin náà, gẹ́gẹ́bí ọ̀gbẹ́ni Reinhardt ti sọ fún wa lọ́dún 2023 kó tó fẹ̀yíntì lẹ́nu isẹ́.

Eyí ló farapẹ́ ìròyìn táà ti sáàjú gbọ́ nípa bí àwọn agbẹjórò ilẹ̀ Amerika ti sọpé olórí ètò àábò oun lówà nidi gbogbo ìwà ọ̀dàràn tó ń wáyé ní Bulgaria sùgbón tíkò forúkọ rẹ̀ síì. ẹ

Ẹrí táà ní tún safihán ọ̀kan o jọ̀kan ìwà gbígbé egbò igi olóró tó pòjù lọ nílẹ̀ Bulgaria niwọ́n tọpasẹ̀ dódò OneCoin oun gẹ́gẹ́bí igbákejì agbejọ́rò ti sàlàyé.

Béè lósì jé wípé olórí ètò àábò yí ló mọ̀sì bí omidan Ignatova ti ráàyè sálọ nígbà tí àsìkò ìjẹ̀jọ́ rẹ nílẹ́ ẹjó ku óla.

Gẹgẹbí ogbẹ́ni Reinhardt ti sàlàyé, ó ní omidan Ignatova jé ojúlówó òdaràn kojá ojú tí àwọn eeyàn fi ń wòó, lórí bíwọ́n ti mú isẹ́ náà bíi isẹ́ pẹ̀lu gbígbé egbó igi olóró loju mejeeji.

Àgbékalẹ̀ isé yi fihàn bí ìwé kan tí wón topasẹ̀ ajọ Europol tó sàtìlẹ́yin fún, tílé isẹ́ BBC sì rí ì wípé lóòtọ ni omidan Ignatova ti Pòóra lọ́dún 2017 sùbgọ́n tí àwọn ọlọ́ọ̀pá ilẹ̀ Bulgaria ti fÌdI Ìbàsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Taki múlẹ̀.

Nípa bí Taki ẹni tì àwọn ọlọpaa furasí tin sàmúlò ojú ìlà OneCoin láti fẹ̀yìn pọn gbogbo owó tíwọ́n ń pa lórí gbìgbé egbò igi olóró bó ti wù ú.

Igbákejì olóòtú ijọba ilẹ̀ Bulgaria Ivan Hristanov sàpéjúwe Taki bíi eni tí eeyán o léè déde rí sójú,nípa bíwọn ti sèwàádí rẹ̀ lọ́dún 2022 lórí bó ti n kún àwọn oṣiṣẹ ìjọba kọ̀ọ̀kan lọwọ huwa ọdaran, bakana lo sọpe wọn ti wọdi rẹ fun awọn iwa bii idigunjale,sise fayawọ ati ipaniyan sugbọn ti wọn ko tii foju rẹ ba ile ejọ fun nnkan kan rara.

Iwadii fihan pe awọn eeyan kan to sunmọ Taki, lo n gbe ile Ruja Ignatova bayii
Àkọlé àwòrán, Iwadii fihan pe awọn eeyan kan to sunmọ Taki, lo n gbe ile Ruja Ignatova bayii

Ile isẹ BBC kọwe sijọba ilẹ Bulgaria nipa awọn osisẹ won to lọwọ ninu iwa ọdaran sugbọn ti wọn ko fesi, bẹẹ ni offisi wọn towa ni olu ilu ilẹ naa iyẹn ilu Sofia sọpe awọn kii fẹyin pọn iwa ọdaran tabi ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ rara.

Iroyin tun fidi ẹ mulẹ pe ilu Dubai ni Taki n gbe lọwọ nibi ti omidan Ignatova ti ra ilegbe olowo nla, ti asuwọn ile ifowopamọ rẹ si n fojoojumọ gba ọgọọrọ owo dolla wọle nipase gbajuẹ sise loju ila OneCoin.

Sugbọn ko sẹni to lee sọ pato ibasepọ towa laarin awọn mejeeji lati ibere pẹpẹ, bee ni awọn kan tun n sọpe o jẹ baba isalẹ fun ọmọbinrin rẹ.

Elomiran to sumọ omidan Ignatova sọ fun ile isẹ BBC pe milliọnu kan Euro lowo to n san fun taki losoosu ko lee maa daabo bo o. Bakana lo tun farahan ninu iwe ajọ Europol wipe wọn fẹ ta ilẹ ori kan ti wọn tọpasẹ dọdọ ile isẹ kan tojẹ ti omidan Ignatova fun iyawo Taki,leyi to fihan pe ọrọ to niise pẹlu owo tun wa laarin awọn mejeeji.

Amọ latọdun 2022 ni orukọ omidan Ignatova tiwa loke tente iwe ajọ FBI gẹgẹbi okan lara awọn mewa ti wọn wa titi doni oloni yi.

Ikọ BBC to n sisẹ lori bi oguna gbongbo obinrin onijibiti ori ila naa, ti ri oniruuru iroyin gba nipa ibi ti arabinrin naa wa lẹyin tiroyin iku rẹ ti saaju gbale-gboko pẹlu bi igbiyanju awọn ọlọpaa to fẹ muu nilu Greece lọdun 2022 ti jasi pabo.

Wọn ni o wa seese kojẹ wipe iroyin iku rẹ niwọn fẹ fi mu ọkan awọn eeyan kuro lori ọrọ rẹ, ati wipe to ba jẹ bẹẹ ni, yi o nira fun un lati farapamọ fun igba pipẹ bọdun ti n gori ọdun si i.

Lọna min, ogbẹni Hristanov sọpe o seese ki Elvis Presley ṣi wa laye,sugbọn ko fi bẹẹ si aridaju ọrọ kan pato lori rẹ.

Ogbẹni Reinhardt tọka sii pe ajọ FBI kii dede forukọ eeyan soke tente iwe awọn eni won n wa lori eré lasan sugbon wọn lee yọ orukọ kuro lẹyin tiwọn ba ti fidi iroyin iku eni naa mule ni tootọ.

Lori ọrọ to niise pelu Ruja Ignatova yi, wọni o seese ko ma ri bẹ́ẹ̀ rara nipa bi wọn kò tii ṣe dawọ ise wiwa rẹ duro rara.