'Ọmọ mi kú láàárín wákàtí mẹ́fà tí wọ́n dúnkokò láti fi fọ́tò ìhòhò rẹ̀ s'órí ayélujára'

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
- Author, Joe Tidy
- Role, Cyber correspondent, BBC World Service
Ìyá kan, ẹni tí ọmọ rẹ̀ pa ara rẹ̀ láàárín wákàtí mẹ́fà tí àwọn tó máa ń lo àwòrán ìhòhò ènìyàn fi gba owó lórí ayélujára ní kí ó lọ mú owó wá, ti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo láti gbógun ti ìwà yìí.
Ní ọdún 2022 ni Jordan DeMay pa ara rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò kan, Samuel àti Samson Ogoshi ní kó mú owó wá tàbí kí àwọn fi àwòrán ìhòhò rẹ̀ sórí ayélujára.
Samuel àti Samson parọ́ fún Jordan pé obìnrin làwọn àti pé ọjọ́ orí àwọn kò ju ti Jordan láti fi gba àwòrán ìhòhò rẹ̀, tí wọ́n sì ní àwọn máa fi àwòrán náà sórí ayélujára tó bá kọ̀ láti fún àwọn lówó.
Ìyá Jordan, Jenn Buta ti wá ń lo ìkànnì TikTok rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn pàápàá àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwà ọ̀daràn yìí tó wọ́pọ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti ń fẹ́ràn àwọn fídíò tó ń fi sórí ayélujára rẹ̀.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà sọ fún BBC News pé àwọn kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìwà ọ̀daràn yìí.
Samuel, ẹni ogún ọdún àti Samson, ẹni ọdún méjìlélógún bá Jordan, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún sọ̀rọ̀ lórí Instagram bíi obìnrin.
Wọ́n fi àwọn àwòrán ìhòhò ọmọbìnrin ránṣẹ́ si, wọ́n sì ní kí òun náà fi àwòrán ìhòhò rẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n ní tí Jordan kò bá fẹ́ kí àwọn pín àwòrán ìhòhò rẹ̀ ránṣẹ́ lórí ayélujára kó fi owó ránṣẹ́ sí àwọn.
Nígbà tí Jordan sọ fún wọn pé òun kò lè rí owó fi ránṣẹ́ sí wọn mọ́ àti pé òun máa pá ara òun, wọ́n ní kó ṣe bẹ́ẹ̀ kíákíá tàbí kí àwọn ràn án lọ́wọ́ láti pa ara rẹ̀.

Samuel àti Samson ti wà ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ báyìí. Wọ́n ń dúró de ìdájọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbà pé àwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.
Jenn sọ fún BBC News pé kò ju wákàtí mẹ́fà lọ tí Jordan fi ń bá àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò náà sọ̀rọ̀ tó fi gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀.
Jenn tó ń sọ̀rọ̀ ní ilé rẹ̀ ní Michigan, orílẹ̀ èdè America, ní níṣe ló dàbí pé wọ́n ti kọ bíi ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò ṣe lọ kalẹ̀ tí wọ́n sì ń fúngun mọ́ ẹni tí ọwọ́ wọn bá tẹ̀.
"Kíákíá ni wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe láti tún tètè mú ẹlòmíràn nítorí bí èèyàn bá ṣe pọ̀ sí ni fún wọn."

Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni wọ́n sábà máa ń fi ìbálòpọ̀ tàbí àwòrán ìhòhò gba owó lọ́wọ́ wọn.
Ní oṣù Kẹrin, àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì ni ọwọ́ òfin tẹ̀ lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ orílẹ̀ èdè Australia kan pá ara rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fẹ́ máa fi àwòrán ìhòhò rẹ̀ gbowó lọ́wọ́ rẹ̀.
Ìwà yìí ti ń wọ́pọ̀ ní Japan tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ló wà nídìí rẹ̀.
Ìwádìí ìwà ọ̀daràn ní Amẹ́ríkà fihàn pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti lékún, tó ti wọ 26,700, tí ó kéré tán àwọn ọmọkùnrin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ti pa ara wọn lórí rẹ̀.
Ní ọ̀sẹ̀ yìí, àwọn onímọ̀ nípa gbígbógunti ìwà jìbìtì lórí ayélujára ní Nàìjíríà yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú àjọ tó ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn UK ní London láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìwà ọ̀daràn orí ayélujára.
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn ní UK lóṣù tó kọjá ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọdé àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ lórí ìwà yìí.
Wọ́n ní àwọn tó máa ń ṣe iṣẹ́ láabi yìí le jẹ́ láti àwọn orílẹ̀ èdè ẹkùn iwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ tàbí láti ẹkùn gúúsù ìlà oòrùn Asia.

Àwọn oníwádìí nípa ètò ààbò orí ayélujára ní ìwà ọ̀daràn ká máa fi àwòrán ìhòhò gba owó lọ́wọ́ èèyàn kò ṣẹ̀yìn àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń ṣe yahoo.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, Iléeṣẹ́ ààbò orí ayélujára kan ní Amẹ́ríkà, Network Contagion Research Institute ṣàlàyé pé àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kan lórí TikTok ń pín àlàyé lórí bí wọ́n ṣe lè máa gbowó lọ́wọ́ àwọn ọmọdé nílẹ̀ òkèrè.
Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn orí ayélujára, Uche Ifeanyi Henry ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn n ṣiṣẹ́ takuntakun láti nawọ́ gán àwọn ọ̀daràn yìí.
"Àwọn tí wọ́n rò pé ìjọba Nàìjíríà kò gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí rẹ̀ kò mọ nǹkankan."
Ó ní bí ìjọba ṣe ná owó tabua láti fi dá àjọ náà sílẹ̀ jẹ́ àfihàn pé ìjọba kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìwà ọ̀daràn orí ayélujára pàápàá fífi ìbálòpọ̀ tàbí àwòrán ìhòhò gba owó lọ́wọ́ èèyàn.
'Àwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ́'
"Ọwọ́ líle la fi ń mú àwọn ọ̀daràn yìí.
"A ti wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ sílé ẹjọ́, tí àwọn míì sì wà ní àhámọ́.
"Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀daràn ọ̀hún ni wọ́n ń sá kúrò ní Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ wá nítorí rẹ̀," Henry ṣàlàyé.
Ìwà fífi ìbálòpọ̀ tàbí àwòrán ìhòhò gba owó lórí ayélujára ṣì ń peléke si, tí àwọn ọ̀daràn náà kò sì yọ ọ̀dọ́ Nàìjíríà sílẹ̀.
Àmọ́ ìwà ọ̀daràn yìí kìí ṣe ìṣòro Nàìjíríà nìkan, kí kojú rẹ̀ nílò àtìlẹyìn àgbáyé.
'Mímu níṣẹ́ gidi'
Ẹ̀wẹ̀, Dókítà Tombari Sibe láti Digital Footprints Nigeria ní ìwà ọ̀daràn lórí ayélujára ti di ohun tó gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà tó ní ìmọ̀ nípa ayélujára àti ìmọ̀ ẹ̀rọ.
Ó ní ohun tó ṣokùnfà rẹ̀ kò ṣẹ̀yìn àìsí iṣẹ́ àti ebi.
"Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ yìí kò ní nǹkankan - ó ti dàbí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, wọn kìí ronú ohun tó lè ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ."
'Pípolongo'
Jenn àti bàbá Jordan ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpolongo tí wọ́n ń ṣe.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti kan sì òun láti wá pàrọwà fún àwọn òbí ní Amẹ́ríkà, Australia àti UK, tí wọ́n ti pàdánù àwọn ọmọ wọn sọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn yìí.
Jenn ní onírúurú àtẹ̀jísẹ́ ni òun ti gbà látọ̀dọ̀ àwọn òbí tó ń bèèrè pé kí ni kí àwọn ṣe nítorí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ àwọn.
"Nígbà mìíràn, wọ́n kàn fẹ́ ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ wọn fún mi.
Ìmọ̀ràn tí Jenn àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò máa ń fún àwọn èèyàn tí àwọn oníṣẹ́ láabi yìí bá ti ṣe lọ́ṣẹ́ ni pé:
- Rántí pé kìí ṣe ẹ̀bi rẹ̀ ni ohun tó ṣẹlẹ̀
- Fi ẹjọ́ ìkànnì ẹni tó fẹ́ máa lù ọ́ ní jìbìtì sùn
- Dènà ẹni náà láti máa túnbọ̀ kàn sí ẹ
- Fi àwòrán àti àwọn ọ̀rọ̀ tó bá kọ sí ẹ pamọ́ láti ran àwọn agbófinró lọ́wọ́ láti ṣàwárí onítọ̀hún
- Gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àgbàlagbà tàbí agbófinró kí o tó fi owó tàbí àwòrán mìíràn ránṣẹ́
- Gbígbà sí àwọn tó ń lù ọ́ ní jìbìtì lẹ́nu kò lè ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan fún ẹ àyàfi àwọn agbófinró.








