Ìwọ́de Shiite: Ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan lo farapa nibi t'awọn musulumi ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Shiiite ti kọlu awọn ọlọpaa lasiko ti wọn n ṣe iwọde nilu Kaduna l'Ọjọru.
Saaju igbẹjọ olori wọn Ibrahim El-zakzaky ti yoo waye l'Ọjọbọ, awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite ṣe iwode lati kepe ijọba pe, ki wọn tu olori wọn to wa lahamọ silẹ.
Iroyin sọ di mimọ pe, awọn ọlọpaa meji wa lara awọn to farapa nibi ti wọn ti n dari awọn to n ṣe iwode naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa Aliyu Mukhtar sọ pe, iwọde naa ko yọ awọn obinrin ati ọmọde silẹ.
Iwọde ọhun pa eto ọrọ aje lara ni opopona Ahmadu Bello, o si tun fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.








