Fulham vs Arsenal: Arsenal lu Fulham ní àlùbami pẹ̀lú 3-0, ṣùgbọ́n ariwo Willian layé ń pa

Lacazette gba goolu rẹ sawọn

Oríṣun àwòrán, Premier league

Nnkan o rọgbọ fun ikọ Fulham ni ipadabọ wọn si idije Premier league ilẹ Gẹẹsi lọjọ Satide pẹlu bi Arsenal ti wọn gba lalejo din dundu iya ni adingbẹ fun wọn ni papa iṣire Craven Cottage to jẹ ibuba wọn.

Goolu mẹta si odo ni Arsenal fi ki ikọ Fulham to ṣẹṣẹ gba igbega wa si premier league lati liigi keji ilẹ Gẹẹsi ti a mọ si Championships kaabọ.

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹsan ni atamatase agbabọọlu ikọ Arsenal, Lacazette lo gba goolu akọkọ wọle fun Arsenal eleyi to fun un ni iyi ẹni to gba goolu akọkọ wọle fun saa liigi tọdun 2020/2021 to bẹrẹ lọjọ Abamẹta.

Bakan naa ni goolu ọhun tun sọ Lacazette di agbabọọlu akọkọ ninu itan premier league ti yoo maa gba goolu akọkọ ni saa liigi kan wọle fun saa liigi meji ọtọọtọ.

Aubameyang ati Willian n yọ ayọ goolu

Oríṣun àwòrán, Premier league

Ni saa liigi ọdun 2017/2018, Lacazette ni agbabọọlu to gba goolu akọkọ wọle lọdun naa ninu ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu Leicester

Agbabọọlu ti Arsenal ṣẹṣẹ ra ni ọsẹ diẹ sẹyin, Gabriel Magalhaesjẹwọ pe Arsenal ko fowo jona pẹlu bi o ṣe gba goolu rẹ akọkọ wọle fun ikọ Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa eleyi to jẹ ifẹsẹwọnsẹ liigi akọkọ ti yoo ti kopa fun Arsenal.

Ni kete ti wọn wọle ni Gabriel ti fori gbe bọọlu gbee silẹ ni igun papa koo gba, iyẹn Corner ti Willian, agbabọọlu tuntun miran ti Arsenal ra lati Chelsea gba soju ile Fulham nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkandinlaadọta.

Gẹgẹ bi iṣe rẹ, balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang naa da si ojo goolu to rọ fun Arsenal ni papa iṣire Craven Cottage nigba ti oun naa sọ goolu kẹta sawọn fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta.

Gabriel gba goolu rẹ akọkọ wọle fun Arsenal

Oríṣun àwòrán, Premierleague

Pẹlu goolu yii, Aubameyang ti gba goolu mọkanla wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla ni ṣiṣẹ n tẹle to ti gba fun Arsenal.

Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ni ni aworan ija laarin agbabọọlu Arsenal meji, Ceballous ati Nketiah ti waye lasiko ti wọn fi n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ naa ni papa iṣire Craven Cottage ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.

Awọn agbabọọlu mejeeji yii wa lara awọn ti akọnimọọgba ikọ naa, Mikel Arteta mu lati rọpo awọn agbabọọlu to ba yọ lori papa bi ifẹsẹwọnsẹ naa ba ṣe n lọ