Paul Sodje: Ọjọ́rùú ló yẹ kó pé ẹni ọdun 55, amọ́ tó kú ikú àìròtẹ́lẹ̀

Fulani darandaran

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ikọ ere idaraya Scrabble ni Naijiria tẹlẹri, Paul Sodje ti ku lẹyin ti awọn afurasi darandaran ji gbe.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Nigerian Scrabble Federation, Akintunde Akinsemola, to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba ni, wọn ri oku rẹ ni agbegbe Idoani ni ijọba ibilẹ Ọṣẹ nipinlẹ Ondo.

Akinṣemọla ni ọjọru to jẹ Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020 ni o yẹ ki Paul Sodje pe ẹni ọdun marundinlọgọta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ikọ Nigerian Scrabble Federation naa pejọ pọ lati ranti ọ̀jọ ibi rẹ lori ẹrọ ayelujara ni ọjọ naa.

Paul Sodje lo dari ikọ Naijiria lọ si idije Alawọ dudu ilẹ Afrika to waye ni orilẹede Zambia ni ọdun 2012.

'' Igba ti wọn ti Paul Sodje lọ san owo ẹmi aburo rẹ ti wọn jigbe ni wọn ko gburo rẹ mọ ''

Nigba to n salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ ni bi ọsẹ meji sẹyin, Akinsemola ni lasiko ti wọn fẹ lọ sin mọlẹbi rẹ to ku ni ipinlẹ Delta, ni wahala naa bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

'' Ibi isinku mọlẹbi rẹ, ni wọn wa ti wọn ti gba ipe wi pe Chris, tii se aburo Paul Sodje, wa ni panpẹ awọn ajinigbe, ti wọn si ni ki wọn mu ọgọrun miliọnu wa lati tu silẹ.''

''Awọn ẹbi ati iyawo Chris Sodje bẹ awọn agbebọn naa lati jọwọ gba miliọnu kan Naira, ti awọn ni agbara lati san.''

''Alami ẹyẹ Scrabble ni Naijiria naa wa gbera pẹlu ọrẹ rẹ, lati lọ san owo ẹmi ti awọn ajinigbe naa beere fun ni agbegbe ti wọn ti ji gbe.''

Alaga ẹgbẹ Nigerian Scrabble Federation ni, lati igba ti wọn ti lọ san owo ẹmi naa ni wọn ko ti gburo Paul Sodje, Chris Sodje ati ọrẹ rẹ to tẹle Paul, lati lọ san owo fun awọn ajinigbe naa.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Akinsemola ni titi di asiko yii, ko si ẹni to le e sọ pato ohun to ṣẹlẹ laarin awọn ajinigbe naa ati awọn ti wọn lọ san owo naa.

O fikun pe, ni ọjọ diẹ lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn darandaran naa tun ṣẹ ikọlu si Idoani, nibi ti wọn ti gbe Adari ileewosan ijọba nibẹ pẹlu awọn eniyan miran lagbegbe naa.

''Lasiko ti wọn n wa awọn eniyan ti awọn darandaran naa jigbe lọ si ileewosan to wa ni ilu Ọwọ, ni wọn ri oku Paul Sodje ati ọrẹ rẹ ni ile igbokusi to wa ni Ọwọ.''

Awọn adari ni ilu Idoani ti Otunba Oladele Olapeju ṣe adari fun ni, wọn ri oku Paul Sodje ati ọrẹ rẹ ni ilu Ajagbale, ti ko jina si ilu Ifọn.''

Darandaran da ẹran wọ inu oko kan

Oríṣun àwòrán, Others

''Awọn lo gbe e oku rẹ lọ si ileewosan ijọba apapọ to wa ni ilu ọwọ titi di asiko yii.''

Mo ti sa gbogbo ipa mi lati ri ọkọ mi ti wọn jigbe pada - Flora Sodje

Nibayii, inu ibanujẹ ni ẹbi ati ara Paul Sodje wa lọwọlọwọ, paapaa iyawo Chris Sodje, Flora, ti ko tilẹ mọ boya ọkọ rẹ wa laye abi o ti ku.

Flora, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni oun ti sa gbogbo ipa oun lati wa ibi ti ọkọ rẹ wa, ti o si fi to gbogbo awọn ẹsọ alaabo to wa ni Naijiria leti.

O ni lati igba ti wọn ti lọ fun awọn ajinigbe naa ni owo, ni awọn darandaran naa ti kọ lati ba awọn sọrọ mọ, ti awọn ko si gburo Chris Sodje to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji titi di asiko yii.

Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati ba ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo sọrọ lori isẹlẹ yii, si lo ja si pabo.