FA Cup final Arsenal vs Chelsea: Lampard laná! Arsenal fa Chelsea ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ gba ife FA Cup

Oríṣun àwòrán, @Arsenal/twitter
Ami ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fi ja ife idije FA Cup mọ Chelsea lọwọ.
Nkan gbona janjan bi amala gbigbona lasiko ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Arsenal koju ara wọn ni aṣekagba idije FA Cup.
Papa iṣere Wembley to jẹ ti Chelsea ni idije na ti waye.
Nigba ti yoo fi di ọgbọn iṣẹju ti idije naa bẹrẹ, Chelsea ati Arsenal ti ku eruku ami ayo kọọkan si ara wọn l'oju.
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo kọkọ gba bọọlu wọle, lati ọwọ ọmọ ilẹ America, Christian Pulisic.

Oun si ni ọmọ ilẹ America akọkọ to gba bọọlu sinu àwọn ni aṣekagba idije FA Cup.
Ṣugbọn Cesar Azpilicueta ṣe aṣiṣe, eyi to mu ki Arsenal o gba pẹnariti.

Pierre-Emerick Aubameyang lo gba bọọlu wọle fun Arsenal, niṣe lo fi bọọlu ju goli si ibi ti ẹgbẹ kan.
Oun naa lo si tun gba bọọlu keji wọle fun wọn ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa.
Chelsea ti kọkọ gba kaadi yẹlo ni abala akọkọ, ti wọn si tun gba omiran laipẹ ti abala keji bẹrẹ.

Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti yege lati kopa ni idije Europa.













