Coronavirus Update: Ebi lé pa ènìyàn 12,000 lójoojúmọ́ lẹ́yìn Covid-19- Oxfam International

Coronavirus: Ebi lé pa ènìyàn 12,000 lójoojúmọ́ lẹ́yín Covid-19

Oríṣun àwòrán, others

Àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba, Oxfam International ti kéde pé, ó ṣee ṣe kí ikú tó jọ́ mọ́ ebi lú ènìyàn ẹgbẹ̀run méjìlá pa lọ́joojúmọ́ lẹ́yìn ti àrùn Colvid-19 bá kásẹ nílẹ̀.

Wọn ni èyí yóò sì fẹ́ẹ̀ ju iye ènìyàn ti àrùn Covid-19 pa lójoojúmọ́ lọ.

Lásìkò tí àjọ náà ń pe ìpàdé akọròyìn ló sàlàyé pé nígbà ti yóò fi di òpín ọdún yìí ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjílà léé maa kú lóòjọ́,

Ó ṣeéṣe kí ènìyàn 12,000 máa kú lójoojúmọ́ lẹ́yín Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyí ju iye ènìyàn ti Coronavirus ń pa lójúmọ̀ lọ lati ìgbà ti ọ ti di rànto nínú oṣù kérin ọdún yìí.

Àjọ náà sàlàyé pé ènìyàn mílíọnù mọ́kànlélọ́gọ́fà ní ó ṣeéṣe kí àrùn yìí tì sínú ìṣẹ́ àti òsì, àiníṣẹ́ àti àìsí ounjẹ, tó fi mọ́ aisi ìpèsè àwọn ǹkan tí ènìyàn fí ń gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́.

Adarí àgbà ilé iṣẹ́ náà, Chema Vera ní "àrùn Covid-19 ni pabanbarì iṣẹ́ nitóri pé mílíọ́nù àwọn ènìyàn ti ń tiraka láti la àsìkò yìí já tẹ́lẹ̀".

O ni pe: oníruurú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó n bá àsìkò yìí rìn lo pọ.

Ati pe ijà (ikọlu, ogun), àyípada ojú ọjọ́, àìdọ́gbà láwùjọ àti bí ètò òunjẹ ṣe dí èyí ti kò tóó pín naa fẹ apero.

Eyi kò si ṣẹyin bi àwọn ilé iṣẹ́ tó n pèsè òunjẹ kò ṣe lágbára mọ.

Alaye lori awọn to ri ṣe lasiko Covid 19:

Ajo Oxfam ni: Síbẹ̀ àwọn tó wà nípò gíga àti ipò òṣèlú ṣì ń lówó sii.

Ati pe àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pèsè òunjé àti òhun mímu fún àwọn tó ní ipín ìdókòwò pẹ̀lú wọ́n ní bílíọ̀nù méjìdínlógun nínú oṣù kíní ọdún yìí,

Ajọ yii ni pe èyí ju ìlópo mẹwàá iye ti àjọ ìsọ̀kan àgbáye sọ pé àwọn nílò láti kó ẹbi àti òsì kúrò lágbàyé"

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

Chema Vera ni: "Kódà àwọn orílẹ̀-èdè ti wọ́n ti gbọ́njú dáadaa bi South Africa, India àti Brazil, ló ṣeẹṣe kí orílẹ̀-èdè wọ́n di olú ilú ebi.

Ni ipari, ajọ OXFAM rọ àwọn ìjọba láti sa ipa wọ́n gidi kí wọ́n kásẹ̀ àrùn Covid-19 kúrò nilẹ̀,

Bákan náà ni wọn ni pe ki ijọba tètè kó ọ̀rọ̀ ebi àti ìṣẹ́ kúrò nilẹ̀ kí ikú tó ní i ṣe pẹ̀lú ebi máa baa gbòde kan lẹ́yìn ti Covid-19 bá kásẹ̀ nílẹ̀.