Estimated Billing: Wo ọ̀nà tí àṣẹ tuntun tí Ààrẹ Buhari pa nípa owó iná gbà kàn ọ

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@BASHIRAHMAD
Aarẹ Muhammadu Buhari ti pe fun fifi opin si bi ilana ti awọn ileeṣẹ amunawa n gba bu owo fun awọn onibaara jakejado Naijiria.
Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Twitter rẹ lo tun ti paṣẹ pe ki ajọ to n ri si ina mọna-mọna pin ẹrọ to n ṣe onka ina, meter, kaakiri Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ko tan sibẹ o, Aarẹ Buhari tun buwọlu u pe ki wọn mase gba owo ori lọwọ awọn to n ko mita wọle lati ilẹ okeere fun ọdun kan, ki awọn ọmọ Naijiria ti ko ni ẹrọ naa le tete ri gba lowo ti ko nira.
Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ, ijọba apapọ ti n ṣiṣẹ lati rii daju pe ileeṣẹ to n pin ina, DisCos, fi ara jin si ṣise afikun si iye wakati ti ina yoo fi ma wa ni oojọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Oore wo lo n bẹ ninu ilana naa fun ọmọ Naijiria?
Ajọ to n mojuto ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria, NERC, ti ṣalaye nipa ilana to yẹ ko mu adinku ba bi awọn ileeṣẹ mọna-mọna ṣe n gba iye owo to wu wọn lọwọ awọn ti ko ni mita.
Service base tariff ni wọn n pe ilana naa. O si tumọ si pe iye ina ti iru awọn eeyan bẹ ẹ ba lo nikan ni wọn o san owo rẹ.
O fi oju han ninu atupalẹ kan ti ajọ NERC fi sita lori ilana naa, nipa bi awọn ọmọ Naijiria ṣe le lo ilana naa lẹyin ti aarẹ Buhari paṣẹ.
- Tarrant tó yìnbọn pa èèyàn 51 ní mọ́ṣálááṣí méjì gbà'dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére
- Wo ojú àwọn afurasí tó fipá bá Uwaila, akẹ́kọ̀ọ́ Uniben sùn tí wọ́n tún pa á sínúu ṣọ́ọ̀ṣì
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Tunde Idiagbon, ọ̀gágun kògbagbẹ̀rẹ́ tó ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ló yẹ kí ológun máa rẹ́rìín
Ajọ naa sọ pe lẹyin ti aṣẹ aarẹ ba bẹrẹ iṣẹ, awọn onibaara yoo ni agbara lori iye ti ileeṣẹ amunawa n gba lọwọ wọn - eyi yoo si mu ki o ka ileeṣẹ DisCos naa lara lati tete pin mita fun gbogbo eeyan.
Bakan naa ni awọn onibaara yoo ni anfaani ibi ti wọn ti le fi ẹjọ sun nipa ileeṣẹ amunawa ti ko ba ṣe daadaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ko tan sibẹ o, ajọ NERC tun sọ pe ilana tuntun naa yoo ri i daju pe ileeṣẹ DisCos ko yan awọn onibaara wọn jẹ, ti iye ti wọn ba n gba naa si gbọdọ pe wọn lati ṣe iṣẹ to dara.
Onimọ nipa ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria, Taiwo Adebulu sọ pe ilana tuntun naa yoo daabo bo awọn talika, ti yoo si mu ki awọn olowo ma a san owo gọbọi fun ina.
Ṣugbọn, o ni o ṣe e ṣe ki ileeṣẹ DisCos o ma a pese ina fun awon to le sanwo rẹ nìkan.
O sọ pe nkan miran to tun wa nibẹ ni pe ko si ilana tabi ofin ijọba kankan nilẹ lati ri i pe DisCos tẹle ilana tuntun naa.
Nigba wo ni DisCos le fi kun owo ina?
·Gẹgẹ bi ajọ NERC ṣe sọ, ileeṣẹ DisCos yoo le fi kun owo ina ti awọn ti ko ni mita n san ti:
·O ba jiroro pẹlu onibaara, to si sọ iye wakati ti wọn o fi ma a ni ina fun wọn
·O gbọdọ fun wọn ni mita
·Awọn ti ko ni mita ko gbọdọ ma a san ele owo to ju iye ti awọn to ni mita n san lọ ni agbegbe kan naa.