Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo dá olóyè Ofiki dúró lórí ìwakùsà lọ́nà àìtọ́

Gómìnà Seyi Makinde jòkòó lórí àga, wọ aṣọ olómi aro, ó gbé gbohùngbohùn síwájú

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ni ki oloye Jacob Adefabi Sobaloju ti agbegbe Ofiki lọ rọkun nile fun igba kan na fẹsun wi pe o tapa si ofin ijọba Oyo lori eto iwakusa ni ipinlẹ naa.

Ijọba ni oloye naa tun fun awọn eeyan kan ni anfaani lati tasẹ agẹrẹ si ofin ijọba lori eto iwakusa paapaa abala 001/2023, iwe ofin to de iwakusa ni ipinlẹ naa.

‎‎Ninu lẹta ti adari ẹka to n ri si ọrọ oye ni ileeṣẹ to ri n si ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ti ipinlẹ Oyo, Olajire Moses Aloo fọwọ si fi ẹsun kan Oloye Jacob Shobaloju pe o n buwolu iwe aṣẹ fawọn ileeṣẹ kan lati maa wakusa ni awọn agbegbe kan atawọn igbo ọba lai gba aṣẹ latọdọ ijọba.

Atẹjade naa fi kun pe wọn ti ni ki Oloye Sobaloju lọ rọkun nile fun igba kan na, ti ko gbọdọ yọju si aafin Onito ti Ito lati ọjọ Karun-un oṣu Kiini Ọdun 2026 titi ti wọn fi maa pari iwadii ti wọn n ṣe lori awọn ẹsun ti wọn fi kan-an.

Ijọba rọ Oloye Jacob Sobaloju lati yẹbaa titi ti abajade iwadii yoo fi jade, ko si ri daju pe oun ko gbe igbesẹ kankan to le ṣakoba fun iwadii naa.

Bakan naa ni wọn ko ri daju pe o n fi ara rẹ kalẹ nigbakugba ti awọn to n ṣe iwadii naa ba ti n pe e fun ifọrọwanilẹnuwo lori ọrọ naa.

‎‎‎‎Labẹ ofin Naijiria, ijọba apapọ nikan lo lẹtọọ lati fun awọn ile iṣe iwakusa lasẹ lati wa kusa nibikibi lorile-ede yii.

‎‎Labẹ abala 44(3) iwe ofin ọdun 1999 ti orile-ede Naijiria, gbogbo ilẹ ti ohun alumoni ba wa kaakiri orilẹ-ede yii lo wa labẹ ijọba apapọ, to si jẹ pe ijọba apapọ nikan lo ni aṣẹ lati fun ẹnikẹni ni anfaani lati wa kusa tabi wa ohun alumọni kankan ninu ilẹ.

‎‎ Eyi ni yoo jẹ igba keji ti ijọba nipinlẹ Oyo yoo ni ki oloye kan yẹbaa lori ipo wọn latari ẹsun to jẹ mọ iwakusa nipinlẹ Oyo.

‎‎Oṣu Keji, ọdun 2024 ni ìjọba Ipinlẹ Oyo ti saaju rọ Onido ti ilu Ido Ọba, Gbolagade Muritala Babalola lati yẹbaa gẹgẹ bi Onido ti ilẹ Ido ki wọn to daa pada ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2024 lẹyin aabo iwadii.