Àwọn ajínigbé tún jí èèyàn mẹjọ gbé ní Kwara

Àwọn agbébọn tó gbé ìbọn lọ́wọ́, fi ọta ìbọn kọ́rùn

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Egbinrin ọtẹ, bi a ṣe n pana ọkan ni omiran n ru.

Awọn ajinigbe tun ṣọṣẹ laaarọ ọjọ Aje, ọjọ Karùn-ún, osu Kìíní ni ipinlẹ Kwara nibi ti wọn tun ti ji eeyan mẹjọ gbe lọ.

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi aago meje owurọ ni opopona Isanlu isin si Omu-Aran gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ.

Gẹgẹ bi ọkan lara mọlebi awọn ti wọn ji gbe Arabinrin Taye Aboyeji se wi, o ni awọn ajinigbe naa da awọn eeyan to lọ ṣọdun nile ti wọn n pada si ibugbe wọn lọna ati awọn ọlọkada to gbe wọn.

O salaye pe, aburo oun wa lara awọn ti wọn jigbe ti awọn sí ti pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ amọ ti ko lọ mọ.

O sọ pe ilu Omu-aran ni aburo oun naa n pada si, to si gun ọkada ṣugbọn ti awọn ajinigbe da wọn lọna, ti wọn si ji gbe lọ.

Lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Kansilọ ilu naa, ọgbẹni Akọlapọ Sunday fidii iṣẹlẹ ijinigbe naa mulẹ.

Ọgbẹni Akọlapọ ni ọkada márùn-ún lawọn ba lẹgbẹ titi ti wọn ti ko awọn eeyan to gun ati ero lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ṣalaye pe ọkan lara awọn ti wọn ji gbe ni orukọ rẹ n jẹ Samson, ẹni to n bọ lati ilu Omu-Aran to si n lọ si ilu Isanlu lati lọ gbe awọn ti wọn n jọ n lọ sibi eto kan ni ilu Ilọrin ni owurọ ọjọ Aje ṣugbọn to kagbako awọn ẹni ibi naa lọna.

Ẹlomii to tun sọrọ nipa iṣẹlẹ yii, ọgbẹni Dare kọminu lori bawọn ajinigbe ṣe n ji awọn eeyan gbe lagbegbe naa, bó ṣe sọ pe ijinigbe naa ti di ohun ojoojumọ.

O wòye pe, "ọpọ èèyàn ni o wale wa sọdun keresimesi ati ọdun tuntun to kọja nitorí ibẹru bojo ijinigbe."

O parọwa si ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ lati seranwọ fun awọn eeyan agbegbe naa lati dẹkun iṣẹlẹ ijinjigbe ojoojumọ.

Ninu ọrọ rẹ, Arabinrin Fọlake Oni sọ pe, koda tọkọtaya kan wa ti wọn jigbe lasiko ọdun keresimesi ti wọn o ti ri wọn bayii.

O ni se ni ọkọ naa mu iyawo rẹ wa sọdun Keresimesi ni ilu abinibi rẹ ko to di pe wọn ko sọwọ awọn ajinigbe naa.

O salaye siwaju si pe awọn mẹrin ti wọn jajabọ lọwọ awọn ajinigbe naa farapa ti wọn si n gba itọju lọwọ ni ile iwosan.