Lagos traffic: Ohun márùn ún tó ń fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ nílùú Eko

awọn ero inu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo eeyan lo mọ pe ninu awọn ilu to tobi lagbaye ni ilu Eko wa.

Fun ọpọlọpọ eeyan, ko si ohun meji to kọkọ n wa sọkan awọn eeyan bi wọn ba gbọ orukọ ilu Eko ju sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lọ.

Ko si idi meji lori eyi ju pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lo n jọba l'Eko. Amọṣa, titi di bi a ṣe n sọ yii, ko tii si ojutu fun un.

Opopona ti ko dara;

Kii ṣe aniani pe ọpọ awọn opopona ni ilu Eko ni ko dara fun lilọ-bibọ ọkọ to ja geere.

Eyi to kun fun ọpọlọpọ koto. Awọn koto wọnyii ni o maa n kun fun omi nigba ojo ti o si maa n fana atogbemulemu awọn ọkọ.

Ọpọ igba ni ijọba ipinlẹ Eko funrarẹ ti jẹwọ pe bi ọrọ ṣe ri gẹlẹ niyi.

Opopona pẹlu goto goriror

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kii ṣe aniani pe ọpọ awọn opopona ni ilu Eko ni ko dara fun lilọ-bibọ ọkọ to ja geere.

Ọpọlọpọ ọkọ:

Gbogbo eeyan lo mọ pe ninu awọn ilu to tobi lagbaye ni ilu Eko wa.

Bi awọn eeyan si ti ṣe pọ to nibẹ naa ni iye awọn ọkọ ti wọn n lo fun irinna pẹlu n pọ sii. Abajade eyii naa ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Opọlọpọ lo maa n gbe ọkọ soju titi lojoojumọ ni eyi to tun n ṣafikun si iṣoro yii.

aworam sunkẹlẹ̀rẹ̀l

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lagos traffic: Ohun márùn ún tó ń fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ nílùú Eko

Aletilapa awakọ àti iwa tani-o-mu-mi:

Ọpọ igba ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ba wa loju popo ni ipinlẹ Eko lo maa n jẹ afọwọfa awọn awakọ.

Ọpọ iwa kokanmi, tani yoo mumi ati aibikita awọn awakọ, yala awakọ ero ni tabi aladani, lo n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Ọpọ awakọ ati awọn ero loju popo lo maa n huwa ti ko tọ laarin titi ati ni ẹgbẹẹgbẹ opopona.

Awon awakọ miran a bọ aṣọ silẹ maa ba ara wọn ja loju popo lai palẹ ọkọ tabi alupupu wọn mọ kuro lọna ki ẹlomii le ri aaye kọja lasiko.

Ọpọ ninu awọn onidanfo a tun duro si aarin titi maa wa ero.

Awọn agbofinro onijẹkujẹ:

Bi o tile jẹ pe a ni ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ rere lawọn ajọ bii ileeṣẹ ọlọpaa, LATMA, bẹẹ naa ni a ni ọpọ to jẹ kọlọransi laarin wọn.

Ṣe wọn si ni eeyan kan lo pari ni ilu ti wọn fi n pe gbogbo ilu ni apari.

Awọn kọlọransi agbefọba wọnyii ni wọn maa n lo ipo wọn ni ileeṣẹ ijọba lati wa bi wọn yoo ṣe gbowo lọwọ awọn awakọ ni tipatipa.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Ijamba loju popo:

Nipasẹ ọna ti ko dara, Aletilapa awakọ, ọpọlọpọ ijamba oju popo ni o n waye loju popo ni ipinlẹ Eko.

Bi ijamba ṣe lee da wahala sunkẹrẹ-fakẹrẹ silẹ niwọnba lo jẹ wi pe aijafafa awọn ajọ gbogbo to yẹ lati tete palẹ oju popo mọ gan an ni ogunnagbongbo ohun gan an to n ṣẹlẹ.

Ọpọ igba ti ijamba ba ṣẹlẹ lopopona awọn oṣiṣẹ bii ti eleto ilera fun iṣẹlẹ pajawiri, panapana, adari ọkọ, atawọn agbefoba miran ni wọn ko ni tete ṣe ohun to yẹ lasiko.

Awọn ọkọ a wa maa to tẹle ara wọn ni eyi to tun maa fa sunkẹre-fakẹrẹ loju titi

Àkọlé fídíò, Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá