New Minimum wage: Ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ sísan N35,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu

Igba ọtun de fawọn oṣiṣẹ ijọba niluu Eko, ijọba ipinlẹ Eko ti ṣetan lati maa san ẹgbẹrun un marun un le lọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣiṣẹ to kere julọ fawọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa.

Koda awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Eko yo rẹrin lọ ile nipari oṣu kọkanla yii, nitori oṣu gan an ni ijọba yoo bẹrẹ si ni san ẹkunwo owo oṣu oṣiṣẹ tuntun.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ tẹlẹ pe ijọba ipinlẹ Eko yoo san ju ọgbọn ẹgbẹrun un naira ti ijọba apapọ kede gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, Hakeem Muri-Okunola lo kede ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita, to si tun fi ṣọwọ sawọn olori ẹka ijọba gbogbo l'Ọjọru

Ọgbẹni Muri-Okunola ni nitori iṣẹ to n lọ lori ẹkunwo owo oṣu oṣiṣẹ tuntun yii ni ko jẹki awọn oṣiṣẹ gba owo oṣu kọkanla yii lọjọ kẹtalelogun ti wọn maa n gba tẹlẹ.

O ni ijọba ipinlẹ pinnu lati san ju owo oṣu ti apapọ gan an n san fawọn oṣiṣẹ rẹ nitori igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lo jẹ ijọba ipinlẹ Eko logun.

Olori awọn oṣiṣẹ rọ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko lati jara mọ iṣẹ wọn, ki wọn si ṣiṣẹ wọn lai ṣọlẹ.

Bakan naa ni Ọgbẹni Muri-Okunola rọ awọn oṣiṣẹ lati fọwọ ṣowọpọ pẹlu ijọba Gomina Sanwo-Olu fun aṣeyọri ijọba rẹ.