Yorùbá dùn lẹ́nu àwọn ọmọ yìí níbi ìdíje ẹgbẹ́ Àtúnbí Yorùbá
Ẹgbẹ Atunbi èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ látàrí àwọn ohun tí kò tọ́ ti a n fojú rí láwùjọ.
Àwọn lọ́ba lọ́ba kò gbẹ́yìn níbi ìdíje náà nítórí wọ́n lòdì sí ìparun èdè Yorùbá.
Ọba Lamidi Adeyemi sọ pé kò sí bí ènìyàn ṣe leè gbọ́ ede Gẹ̀ẹ́sì dáadáa tó, tí kò bá peregede nínú ede abínibí rẹ, kò já mọ́ ǹkankan.

Kábíyèsí ni ede Yorùbá dára púpọ̀, ''Pọ́ńbélé Yorùbá ni mí, n ò sì ní tijú rẹ níbikíbi''. Ó tẹ̀síwájú pé 'ẹ jẹ́ ká ko àwọn ọmọ wa lédè Yoruba to dan mọ́ran'.
'A gbudọ rán BBC Yoruba lọ́wọ́ láti gbé Yorùbá ga'. Kábíyèsí gbé osuba káre fún Iléesẹ́ BBC

Aṣojú ilé iṣẹ́ BBC Yorùbá, Jelilat Opẹyẹmi Ọlawale tó jẹ́ alámójúto ìtàkùn ìkànsíra ẹni lójú òpó BBC Yorùbá tẹnu mọ́ pàtàkì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ojogbon ninu èdè ati asa Yoruba pelu BBC Yoruba. ''BBC Yoruba ti dé fún ògo Yorùbá àti igbe lárugẹ èdè àti àṣà Yoruba pelu awon eto mii tí a ní lọ́jọ́ iwájú bíi idije, ààyè àti ojúlówó ìròyìn ti o je òótọ́''.
Àwọn ìhùwàsí tí kò bójúmu bii ìwà ibaje tí gbilẹ̀ nílé ẹ̀kọ́, ilé ẹ̀sìn, ádúgbò, laarin ìlú, lariwa, gusu, ìlà oòrùn àti ìwọ oòrùn, ọ̀nà láti wá ojútùú sì, ló bí ẹgbẹ́ Atunbi Yorùbá.

Alága ẹgbẹ́ Àtúnbí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayọde Oyediran, sọ pé "lẹ́yìn àròjinlẹ̀ ni a rí pèé ogúnlọ́gọ́ ọmọ Yorùbá, lọ́mọdé àti lágbà lo ti kọ àṣà àti ìṣe Yorùbá sílẹ̀, tí kò sì ìwà ọmọlúàbí l'áwùjọ mọ́."
"Àwọn ọmọ kò lè sọ èdè abínibí wọn mọ́."
Ó ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ Atunbi dá dúró gedegbe, ó sì ń ṣe igbe lárugẹ àṣà, kò fi ti òṣèlú àti ẹ̀sìn ṣe.

Ẹgbẹ́ yìí ń gbìyànjú láti gbé ìlànà tí ọmọ Yorùbá yóò fi ní ìrírí àṣà, ìgbéga fún sísọ àti kíka èdè Yorùbá, wọ́n sì fẹ́ ṣe àwárí ìmúpadàbọ̀sípò àti tí tẹ́wọ́ gba ìwà ọmọlúàbí l'áwùjọ.
Ọjọ́ ọ̀la èdè Yorùbá ti ń kùnà, nítorí nàá ni a ṣe gbé ìdíje kalẹ̀ fún àwọn ọmọ iléèwé l'édè Yorùbá.

Àwọn iléèwé láti ìjọba ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tó wà ní Ibadan ló kópa níbi ìdíje nàá tó wáyé lọ́gbà Fáṣitì Ìbàdàn.
Alága ètò nàá, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ Bámgbóṣé nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé ó ṣe pàtàkì láti náàní "nkan tí a ná, ṣùgbọ́n nítorí pé ó jẹ́ èdè wa, a kó kọbi ara sii.

Ó sọ pé "ọ̀nà kínní ona tí èyí fi ń jẹyọ ni pé ọ̀pọ̀ òbí kìí sọ èdè Yorùbá sí àwọn ọmọ wọn, bíkò ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Bamgboṣe rọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti Yorùbá láti jẹ́ kí èdè Yorùbá mú igbà orókè láwùjọ wa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ijó àti eré ìdárayá ni àwọn èwe fi dá àwọn akópa lára yá.















