NSCDC ṣèèṣì yìnbọ̀n pa ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS l'Osun

Awọn ẹṣọ NSCDC

Oríṣun àwòrán, NSCDC

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ abo ara ẹni laabo ilu, NSCDC, Sunday Dade ṣeeṣi yinbọn pa ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS kan Seyi Adebowale nipinlẹ Osun.

Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o ṣẹlẹ ni aafin ọba to wa ni Kuta, ijọba ibilẹ Ayedire nibi ti Gomina Adegboyega Oyetola ti lọ ṣi afara kan ti ileeṣẹ ọmogun ilẹ kọ.

Ohun ti a gbọ ni pe Dade n yinbọn soke pẹlu idunnu nigba ti wọn n ṣi afara naa lẹyin naa ni ọta ibọn ti ṣeeṣi ba Adebowale.

Agbẹnusọ fun ajọ NSCDC, Adigun Daniel to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe eṣi lo ṣe fun Dade, ko mọọ mọ yinbọn fun un.

O ṣalaye siwaju sii pe Dade ti n jẹjọ bayii lori iṣẹlẹ naa.

Ọga agba ileeṣẹ ọmogun ilẹ ni Naijiria, Tukur Buratai naa wa ni ibi ayẹyẹ ṣiṣi afara ọhun.