Akure Shootings: Bí àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ APC àti PDP ṣe ṣe ara wọn léṣe rèé

Oríṣun àwòrán, theelitetimes.com.ng
Ọkunrin kan ti ko tii si aridaju orukọ rẹ ni iroyin sọ pe wọn pa nibi ija to bẹ silẹ laarin awọn alatilẹyin gomina ipinlẹ Onodo, Rotimi Akeredolu ati awọn ti oludije ẹgbẹ alatako ni Ondo iyẹn PDP, Eyitayo Jẹgẹdẹ.
Iforigbari naa waye ni agbegbe Obanla nilu Akure ti ọpọlọpọ eeyan si farapa yatọ fun eeyan kan ti o fori laku.
Eeyan kan ti iṣẹlẹ yii ṣoju rẹ ni fun ọpọlọpọ wakati ni ilọsoke ilọsodo ati katakara ni agbegbe naa fi kawọ gbera tori igboro to daru.
Ati ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo n di ẹbi iṣẹlẹ yii ru ara wọn lori.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Laipẹ yii ni eeyan marun farapa lasiko ti ẹgbẹ mejeeji yii kan naa doju ibọn kọ ara wọn ni ilu Oba-Akoko ti awọn alatilẹyin ẹgbẹ mejeji farapa yanayana ti ọpọlọpọ ọkọ si ba jẹ
Lara awọn fọnran to jẹyọ lori ayelujara twitter ni awọn wọnyii
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ọpọ awọn eniyan Ondo lo ti n ke gbajare pe ki awọn oludije dupo gomina lati pe awọn alati lẹyin wọn sabẹ nitori pe idibo kii ṣe ogun .
Wọn ni igba akọkọ ree ti iru iwa jagidijagan yii yoo ma waye ni ipinlẹ Ondo.
Nigba ti BBC Yoruba kan si ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, agbẹnusọ ajọ naa Teeleo Ikoro salaye pe nkan bi aago mẹjọ abọ alẹ ana ni awọn gba ipe pe awọn ẹgbẹ kan n ja.
O ni loju ẹsẹ naa ni awọn gbẹra pẹlu aṣẹ kọminsọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa lati lọ se iwadii.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni nigba ti awọn de ibẹ, nkan ti awọn ri ni pe, ati awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ati ti PDP naa ni wọn n ja.
O ni wọn bẹrẹ si ni dana jọ si titi, sugbọn ọlọpaa tu wọn ka ni ana, ti awọn si fi awọn ọlọpaa sọ ibẹ, Sugbọn wọn tun pada wa lonii.
Ikoro ni ko si ẹni to ku ninu ija naa, bakan naa lo fi ọkọ awọn ara ilu balẹ to ba di asiko idibo, awọn ọlọpaa n bọ lati awọn ipinlẹ Naijiria to ku lati ku ọlọpaa ipinlẹ Ondo lọwọ.












