Ondo Election 2020: Mo ṣèlérí N500 lóṣooṣù fún gbogbo ọmọ tuntun - Adeleye AAC
Bo tilẹ jẹ pe o ti to ẹgbẹ oṣelu mọkanla taa gbọ pe o ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Ondo fun idibo gomina to n bọ, awọ oludije ṣi sọ afojusun wọn fun BBC Yoruba.
Adekunle Peter Adeleye ni oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC to si jẹ ọmọ bibi ilu Itibukunmi ni Ilaje, Ondo.
Funrarẹ naa lo fi n fọwọ sọya ara rẹ pe "olootọ eeyan ni Adekunle Adeleye jẹ to jẹ pe to ba sọ bẹẹ, o maa n ri bẹẹ".
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Ta ló da 'ewé' bo N4.3bílíọ́nù owó ìjọba Ondo fọ́dún mẹ́wàá?
- Àwọn olùpolongo ìdìbò Aketi àti Jegede ń forígbárí l'Ondo, bí wọ́n ṣe n yìnbọn ni wọn n sun táyà
- Ṣé lóòtọ́ ni ẹgbẹ́ òṣèlù mọ́kànlá darapọ̀ mọ́ PDP l'Ondo láti gbárùkù ti Jegede?
"Eto ipese ẹẹdẹgbẹta naira lao maa fi pamọ fun gbogbo ọmọ ikoko lati ọjọ ti wọn ba ti bi i.
O ni igba ti ọmọ yoo ba fi gbọnju di bii ọmọ ọdun mejidinlogun, owo naa yoo ti maa wọ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun eyi to to bẹrẹ okoowo tabi san owo ile iwe fasiti bo ba ṣe pe iwe ni ọmọ naa n ka.
Aeleye kẹnu bọ ọrọ lorii bi ipo ipinlẹ Ondo ni ilẹ Yoruba gẹgẹ bi aṣaaju gẹgẹ bo ṣe sọ ọ.