Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọjọ́ àkọ́kọ́ tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

Àkọlé fídíò, Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

"A o wa agbara, ipo, a o wa ọla ku ọla ti a ti ni, a o fẹ di ọlọla julọ ṣugbọn a fẹ ki gbogbo eeyan ni iriri ijọba".

Dotun Ojon to jẹ oludije gomina ipinlẹ Ondo ni ẹgbẹ oṣelu YPP ni iṣoro bii ọna, ina mọnamọna ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn yoo ṣe.

O ni kii si ki n ṣe toripe o wa sọkan awọn lati ṣe ṣugbọn toripe awọn araalu nilo rẹ.

"A fẹ ṣe kaadi igbelu fun gbogbo ara ipinlẹ Ondo".

Lasiko iṣejọba rẹ, Ojon ni ijọba yoo maa san ida marinlelogun ninu owo ileewe awọn akẹkọọ fasiti to jẹ ọmọ bibi ilu Ondo.

O ni ọrọ sisan owo ileewe gọbọi maa n pa awọn eeyan lara bi wọn ba lọ kawe ni ileewe giga kan ti kii ṣe ti ipinlẹ wọn gangan torinaa o ni ijọba yoo ṣe iranwọ lori eyi.

O ni o yẹ ki gbogbo nkan ti ijọba ma ṣe jẹ nkan to jẹ awọn araalu logun bẹẹ gẹlẹ si ni ẹgbẹ oun yoo ṣe.

Dotun Ojon jẹ ẹ̀ni ọdun mejidinlaadọta to n gbe apoti ibo oludije gomina Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party, YPP.