Ondo Election 2020: Rotimi Akeredolu ní ọmọ to ṣe dáadáa, ó yẹ kó ṣe e lẹ́ẹ̀kan síi
"..ko sẹni to le joko ko maa ka a, ko lonka nkan taa ti ṣe. mi ro pe ọpọlọpọ idi lo yẹ ka janfani ati pada wa.
Rotimi Akeredolu to jẹ oludije gomina ipinlẹ Ondo lab asia ẹgbẹ oṣelu PDP to si tun jẹ oun lo wa lori oye bayii ni oun lero pe gbogbo idi lo fi yẹ ki awọn fi lanfani lati pada wa ṣejọba ipinlẹ Ondo.
"Ọdun mẹrin o tii lọ, a ṣi ni oṣu bii marun sii, koda baa ba dibo tan a ṣi ni titi di inu oṣu keji ọdun to n bọ". Akeredolu ni awọn nkan ti awọn ṣe diẹ o to pe ki wọn maaki awọn pẹlu igboriyin.
"Bo tilẹ ṣe ida aadọrin ninu ọgọrun, o yẹ ki wọn fun wa ki wọn si fun wa ni aye lati wa pari rẹ"
Akerdolu ni "awọn kan buru, wọn ṣonu to bẹẹ ti wọn ba de ijọba wọn a pa iṣ ti ẹni to wa nibẹ tẹlẹ ti ṣe ti ṣugbọn awa o ki n pa a ti".
Aketi ni ẹgbẹ APC ti ṣe anfani fun ipinlẹ Ondo. Torinaa bii ti ipinlẹ Eko, o gba awọn ara Ondo nimọran ki wọn jẹ ki APC tẹsiwaju lati ṣe wọn loore.