10,000 Police constables: Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ètò ìgbanisíṣẹ́ tí ọgá ọlọ́pàá ṣé lọdun 2019

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ọrọ ti di maa kẹru rẹ pada sile fawọn ọlọpaa ẹgbẹrun mẹwa, ti ọga agba ọlọpaa Naijiria ṣeto igbanisiṣẹ fun lọdun 2019.
Eyi ko si sẹyin bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ni Abuja ti ṣe wọgile eto igbaniṣiṣẹ ti wọn fi gba wọn wọle ni 2019.
Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ kalẹ lori ọrọ yii ni, ọga ọlọpaa Mohammed Adamu ko laṣẹ tati ṣeto igbanisiṣẹ.
Wọn ni ajọ to n ri si ọrọ akosọ ileeṣẹ ọlọpaa, Police Service Commission, lo laṣẹ lati ṣeto igbaniwọle siṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fanfa lori ọrọ yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ nitori loṣu Kẹsan ọdun 2019 ni ajọ to n sakoso ileesẹ ọlọpaa (PSC) ti gba ileẹjọ lọ, lati le fidi agbara wọn mulẹ, nipa gbigba eeyan ṣiṣẹ ọlọpaa.
Ababọ ẹjọ ti wọn pe ni pe, ile ẹjọ giga Abuja dajọ are fun ọga ọlọpaa, Adamu ṣugbọn PSC faake kọri, ti wọn si gba ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Adajọ Olabisi Ige, to jẹ adajọ to lewaju ninu idajọ naa ni iwe akoso isẹ ọlọpaa lo fun ajọ PSC ni agbara, lati le gba eeyan ṣiṣẹ ọlọpaa.
Ile ẹjọ ni ilana iṣakoso to ni pe ọga ọlọpaa lo ni aṣẹ lati gba eeyan ṣiṣẹ ko fẹsẹmulẹ, nitori naa igbaniṣiṣẹ yii ko bofin mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò bújúmu kí owó epo ní Nàíjíríà dínwó ju ti Saudi lọ - Buhari
- Bọ́ síta láti ṣe ìwọ́de mọ́ ìjọba Nàìjíríà lónìí, ko rugi oyin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ẹ̀yin ọlọ́pàá 10,000 tí ọ̀gá ọlọ́pàá gbà ṣíṣẹ́ ní 2019, ẹ padà sílé - Iléẹjọ́ pàṣẹ
- Ọjọ́ ìbí bàbá mi ni aàrùn ọkàn ṣekúpa màmá mi lójijì- Davido
- Ìjọba Kwara kéde ọjọ iwọlé àwọn akẹkọọ lẹyìn ìséde Covid 19!
- Ọ̀pọ̀ aráàlú Owo wà nílé ìwòsàn, síbẹ̀ APC àti PDP kò gba ẹ̀bi
- Makinde gba àwọn òṣìṣẹ́ LAUTECH 41 tí ìjọba Ajimobi dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ padà
- Obabinrin Elizabeth kejì kí Nàìjíríà kú oríire òmìnira ọgọ́ta ọdún













