Delta Accident: Orí yọ dírẹ́bà ọkọ̀ tó jóná ráúráú ní Delta

Delta

Oríṣun àwòrán, Google

Awakọ kan jajabọ lasiko ti ọkọ rẹ gbina ni opopona PTI Junction, ni ijọba ibilẹ Uvwie, ni ipinlẹ Delta.

Awakọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Moses Palmer ni iṣẹlẹ naa waye ni owurọ Ọjọ Satide.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni dirẹba naa tiraka lati ko awọn nkankan to ku lara ọkọ naa ti o ti le wulọ, lẹyin to ti jọna tan.

Awọn ẹbi ati ara awakọ naa lo pejupese si ibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si n dupẹ pe awakọ naa ko ba iṣẹlẹ oun lọ.

''Arakunrin Palmer n mura lati lo gbe awọn eniyan ọgbọn ti wọn fẹ wọ ọkọ naa lọ si ibi ayẹyẹ, ko to di wi pe o bẹrẹ si ni gbo oorun bẹntirol ninu ọkọ''

''O wa ọkọ naa gunlẹ, to si lo ṣi ibi éngine'ọkọ, ni eefi ba yọ, ti ọkọ naa si gbina.''

Dirẹba naa ni awọn to wa ni ayika ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ gbiyanju lati pa ina naa, amọ ẹpa ko boro mọ, nitori gbogbo ọkọ naa ni o jọna raurau.

Arakunrin Palmer naa ni oun ko mọ bi ori ṣe ko oun yọ ti oun ko ba ijamba ina naa lọ.

Amọ, o wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati dide iranwọ fun oun nitori ọna kan soso ti oun gba fi tọju ẹbi ati ara oun niyẹn.