Onímọ̀ nípa ìhùwàsí: ibi a gbé dàgbà níi ṣe pẹ̀lú ìhùwàsì

Òbẹ ti o gun ara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aisan ọpọlọ ni ki eniyan o maa gbonara nigba ti ọba ni ija pẹlu olubagbe rẹ

Afurasi obinrin agbẹjọrọ kan ti gun ọkọ rẹ pẹlu ọbẹ titi tó fi papoda, o tun rẹ́ nkan ọmọkunrin rẹ̀ lée lọwọ ni agbegbe Diamond Estate, Ajah ni ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ fun ile ise ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Chike Otti, sọ pe isẹlẹ naa to waye laago meje abo, owuro Ọjọbọ ni wọn ni o buru ju nkan ti eniyan le mẹnu ba lọ.

Ọkunrin to doloogbe naa, Otike Odibi, wa lati ilu Delta. Iṣẹ́ agbẹjọrọ ni o n ṣe pelu iyawo rẹ. O ti fẹ obinrin naa lati ọdun mẹta ti ko sì sí ọmọ kankan laarin wọn.

Awọn ti ọrọ naa soju Wọn ni ọkunrin naa ti sọ ọ́ bi ọjọ meji sẹyin pe iyawo oun ń dún kooko mọ́ oun pẹlu ọbẹ nitori iwe ogún ti o fẹ ṣe fun ọmọ rẹ̀ lati ọdọ iyawo tó kọ silẹ, ki o to fẹ oun.

Kini o le fa a ki toko-tayo yọ ọbẹ si ara wọn?

Onimọ nipa ihuwasi ọmọniyan, Abileko Racheal Ọlaniyan, nigba to n sọrọ pẹlu BBC Yoruba gẹgẹ bi onimọ nipa iru isẹlẹ bẹẹ ni ibi ti eniyan gbe nigba to n dagba nii sẹ pẹlu ihuwasi rẹ nigba to ba dagba.

Abilekọ Racheal ni, aisan ọpọlọ ni ki eniyan o maa gbonara nigba ti o ba ni ija pẹlu alabagbe rẹ.

Àkọlé fídíò, Ibi a gbé dàgbà ní se pẹ̀lú ìhùwàsì - Onímọ̀ nípa ìhùwàsí

Onimọ nipa ihuwasi eniyan naa wa parọwa si gbogbo ọkọ ati iyawo lati gbe ninu ifẹ ati lati lọ si ile iwosan fun itọju to peye nigba kugba ti a ba ri awọn ihuwasi ti ko yẹ ọmọluwabi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: