Aṣọ àti bàtà tọ́ka sáwọn afurasí gbéwiri lábúlé Bugaje

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn géńdé mẹ́ta d'èrò ilé ẹjọ́ látàri bàta àtí aṣọ ti Sani, ọ̀kan lára àwọn afurasí ọ̀daràn bọ́ sílẹ̀
Owọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́ta níbi tí gbéwiri ti ṣọṣẹ́ ni Nassarawa Bugaje nijọba ibilẹ́ Jibia ìpínlẹ̀ Katsina.
Awọn mẹtẹẹta naa ni Aminu Usman to jẹ ọmọ ọdún mẹẹdọgbọn, Ibrahim Iliyasu to jẹ ọgbọ̀n ọdun àti Abdulrahman Umar to jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn.
Sani ni àwọn agbofinro kọ́kọ́ mú latari bata ati aṣọ rẹ̀ ti wọn kó nibi ti olè ti fẹ́ jí alupùpù Ogbẹni Tasiu Bello lọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, labule Nassarawa Bugaje, ki wọn to lọ mu Iliyasu ati Umar lẹyin ti wọ́n fọrọ wa Sani lẹ́nu wò tán.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọlọ́pàá ṣàlàyé fún Adajọ n'ile ẹjọ kekere ti Katsina pé ni abule Tsen Kura ni wọn ti gbiyanju lati já ọ̀kadà Bajaj gba lọwọ Tasiu Bello ko tó pariwo s'ita f'araye.
Wọ́n ni nibi ti ó ti ń kigbe ni awọn ara abule ti wa ti àwọn oniṣẹ́ ibi yii sa lọ.
Sani yán aṣọ àti bata sọnù pẹlu ọ̀bẹ nibi to ti ń sá lọ. Èyí ti àwọn agbófinró fi tọpinpin rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adajọ Hajiya Fadile Dikko sún ìgbẹ́jọ́ naa siwaju nigba ti ọ́gá ọlọ́pàá Sani Ado beere fun asiko lati ṣe iwadii siwaju síi.












