Ààrẹ Buhari padà sílé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Trump

Ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari gúnlẹ̀ pádà sí Nàìjíríà

Lẹ́yìn ìbẹ̀wo isẹ́ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbi tó ti fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ fún ìbásepọ̀ pẹ̀lú ààrẹ Donald Trump, ààrẹ Muhammadu Buhari ti padà dé sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lálẹ́ ọjọ́rú.

Ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari padà sílé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Trump

Ìròyìn tó ni létí pé, ọkọ̀ bààlù tí ó gbé ààrẹ àtàwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ẹ̀ gúnlẹ̀ sí apá kan tó wà fún ààrẹ́ ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe nílu Abuja ní ǹkan bí ago mọ̀kànlá ku ìsẹ́jú márunlélógún alẹ́.

Lára àwọn tó kí ààrẹ Buhari kú àbọ̀ ní pápákọ̀ òfurufú ni Mínísítà fún olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Malam Musa Bello, olórí àwọn ọmọ ogun sí ààrẹ, Malam Abba Kyari àtàwọn olóri àwọn òsìsẹ́ aláàbò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Gbajúgbajà òsèré tó tún mọ́ ọbẹ̀ sè