Ó le gan lásìkò ológun, kí ìjọba wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo ọjọ́ kẹta osù káàrún ni gbogbo àgbáyé máa ń se àyájọ́ ọjọ́ oníròyìn. Àjọ ìsọ̀kan àgbáyé, UN, ló kéde rẹ̀ nínú osù kéjìlá ọdún 1993 látàrí àfẹnukò níbi ìpàdé àpapọ̀ àjọ UNESCO.
Ọjọ́ náà jẹ́ ànfàní láti:
- Se àjọyọ̀ àwọn àlàkalẹ̀ òfin tó de ẹ̀tọ́ àwọn oníròyìn
- Láti lè lo ẹ̀tọ́ àwọn oníròyìn káàkiri àgbáyé
- Dá àbò bo àwọn oníròyìn nípa dídádúró wọn
- Kí wọ́n sì bọlá fún àwọn oníròyìn tó pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́nu isẹ́.
Ẹ̀wẹ̀, onírúurú ni ìpènijà tí àwọn oníròyìn ńdojú kọ tó sì ńtàbùkù bá aseyọrí isẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ó se jẹ́ wípé láì sí àwọn oníròyìn tàbí ọ̀nà àti rí ìròyìn kà, kò sí ìròyìn, lára rẹ̀ ni ẹ̀tọ́ láti sọ ìròyìn.
Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ ilú Òkò, Benjamin Obioha tó bá ikọ̀ ìròyín BBC sọ̀rọ̀ mẹ́nu ba síi lára èyí tó wọ́pọ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Ọ̀RỌ̀ OWÓ OSÙ
Ọ̀gbẹ́ni Benjamin sọ̀ wípé eléyìí máa ń de ọ̀pọ̀ onísẹ́ ìròyìn lọ́nà àti sòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ wọn láwọn orílẹ̀èdè tó sẹ̀ ńdàgbà nílẹ̀ Áfíríkà kìí r'ówó pa.
Gbígba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ ohun kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńsọ pé ó wọ́pọ̀ láàrin àwọn oníròyìn pàápàá wọ́n ń torí ẹ̀ pa òtítọ́ mọ́. Sùgbọ́n Benjamin sọ̀ wípé àwọn ilé isẹ́ ni kò san owó gidi fún wọn.
Ẹ́NI TÓ NI ILÉ ISẸ́
Ìsoro 'èmi ni mo ni ilé isẹ́ nítorí náà ẹ ó se bí mo se fẹ́' náà kò jẹ́ kí àwọn oníròyìn se isk wọ́n bí isẹ́. Nítorí ẹni tó ni ilé isẹ́ leè sọ ohun tí ó fẹ́ kí àwọn oníròyìn àti ohun tí kò fẹ́ kí wọ́n sọ.
ÀBÒ
Láìpẹ́ yìí, ogójì ènìyàn ló gbkmi mì ní Afghan níbi tí wọ́n ti se ọsẹ́ tí mẹ́wàá nínú wọn sì jẹ́ onísk ìròyìn.
Àbò àwọn oníròyìn jẹ́ ìsòro ńlá tí àwọn onísẹ́ ìròyìn ńkojú gẹ́gẹ́ bí wọ́n se ńsisẹ́ wọn.
Ọ̀gbẹ́ni Benjamin sọ wípe "ó le gan lásìkò ológun sùgbọ́n níbáyìí, ó yẹ kí ìjọba wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá".












