"Awọn ọ̀dọ́ ní Owo lù àwa Hausa, ba ọ̀pọ̀ ọjà wa jẹ́ torí ìkọlù Agbébọn"

Àkọlé fídíò, Owo Church Attack: Àwọn Hausa sọ̀rọ̀ lórí wàláhà tí wọn kojú lẹ́yìn ìkọlù agbébọn
    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, Akọroyin BBC

Oniruuru isoro ni awọn ẹya Hausa to wa nilu Owo koju lẹyin ti awọn agbebọn ya wọnu sọọsi lati pa ọpọ eeyan lọjọ Aiku.

Awọn ẹya Hausa naa, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, salaye pe ni kete ti isẹlẹ naa sẹlẹ ni awọn ọdọ ilu Owo ti ya wọnu ọja lati wa fi iya jẹ awọn.

Awọn Hausa mejeeji to ba wa sọrọ ni ọpẹlọpẹ ọrọ ti gomina Akeredolu sọ lẹyin isẹlẹ naa lọjọ Aiku, lo tun mu ki ikọlu si awọn lọ silẹ.

“Ọjọ pẹ ta ti wa nibi, ilu yii ni mo ti ka ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, bẹẹ ni ko si ija laarin awa atawọn Yoruba nilu Owo.

Amọ lẹyin ikọlu awọn agbebọn si sọọsi lọjọ Aiku, ni awọn ọdọ n pariwo pe awọn afurasi Fulani lo wa sisẹ ibi naa.

Wọn ko si mọ pe iyatọ wa laarin awa Hausa ati Fulani, idi ree ti wn se wa ya bo wa,wọn ba ọja wa jẹ, eyi to jẹ owo iyebiye.

Ọpọ awọn Hausa to wa nilu Owo ti sa lọ bayii nitori wọn ko fẹ ki awọn ọdọ ilu yii pa awọn.”

Awọn Hausa naa wa n fi ọwọ gba aya pe awọn yoo se ohunkohun ti ilu Owo ba n fẹ lati jẹ ki alaafia jọba.