Awakọ̀ pa òṣìṣẹ́ adárí ọkọ́ n‘Ibadan, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá faraya

Aworan Warder

Oríṣun àwòrán, Google

Rogbodiyan bẹ silẹ ni agbegbe New Garage, Challenge ni ilu Ibadan lẹyin ti awọn ọlọpaa wọ ibẹ lati wa awọn awakọ ti wọn fẹsun kan pe o pa oṣiṣẹ oju popo.

Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade ti wọn fi lede ni arakunrin Oluniyi Bamidele ni orukọ oṣiṣẹ ti wọn pa naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede naa ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ti ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

‘’Iwadii fihan pe ni Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni oṣiṣẹ irina oju popo, Oluniyi Bamidele ti oun ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ni Challenge Ibadan n ṣiṣẹ rẹ lọ ni nigba ti ọkan lara awọn oni maruwa(micra) tako ofin oju popo.''

''Lẹyin naa ni onimaruwa naa kesi awọn ekeji rẹ ti wọn si ṣekọlu si oṣiṣẹ oju popo naa.''

''Wọn ti ọkunrin naa si ẹnu ọkọ to n bọ, ti oni maruwa miran si tun tẹ mọlẹ to si ku loju ẹsẹ.''

Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni iwadi ti bẹrẹ ni kiakia ti igbakeji kọmisọnna to n risi ̣ọrọ iwa ọdaran si ti paṣẹ ki wọn tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Bakan naa lo paṣẹ fun wọn lati wa gbogbo ẹni to lọwọ ninu isẹlẹ laabi yii, ki won si fi wọn jofin.

Wọn wa parọwa si awọn araalu lati ma ṣiṣẹ wọn ni alaafia nitori alaafia ti pada si ibẹ, lẹyin ti wọn kesi awọn oṣiṣẹ ọlọpaa lati rip e alaafia pada si agbegbe naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tun bẹbẹ lọwọ awọn araalu lati fi to awọn leti ti wọn ba ri iroyin to ba le tọkasi iṣẹlẹ naa ati iwadii to n lọ lọwọ lori awọn to pa oṣiṣẹ oju popo naa.

Àkàrà tú s'épo! Ọlọ́pàá mú òṣìṣẹ́ LAWMA tó dibọ́n pé ajínigbé gbé òun lọ Abuja
Sheidu ati Rahaman

Awọn Ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti ipinlẹ Eko ti fi panpẹ ofin mu Arakunrin kan Rafiu Rahaman ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to parọ pe awọn ajinigbe ji oun gbe lọ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi sita ti alukoro wọn Benjamin Hundeyin fọwọ si, oṣiṣẹ ileeṣẹ to n boju to idọti ni Eko ni arakunrin naa.

Wọn ni lẹyin ti Rahaman ni wọn ji oun gbe tan lo tẹ ọkọ leti lọ si agbegbe Lugbe ni ilu Abuja.

Ṣe ni Rahaman ṣe fidio ara rẹ ninu ahamọ ainigbe to si fi ranṣẹ si awọn akẹgbẹ rẹ nibi iṣẹ. Ẹni ti wọn jọ pawọpọ ṣe iṣẹ ibi naa, Usman Sheidu ẹni ọdun mejilelọgbọn beere fun Miliọnu marun Naira amọ o ri ẹgbẹrun lọna aadọjọ gba lẹyin ọpọlọpọ idunadura. Ọwọ ti tẹ oun naa bayii.

Bawo ni wọn ṣe ri Rahaman mu l'Abuja?

Iwadii fihan pe Usman Sheidu ti Ọlọpaa mu ni ilu Abuja pawọpọ pẹlu Rahaman lati dibọn bii pe awọn ajinigbe lo gbe e ti wọn si jọ ṣe fidio ti wọn fi ranṣẹ si awọn akẹgbẹ rẹ ni Eko.

Usman naa ti jẹwọ pe oun ati Rahaman ni awọn jọ pin owo idoola ẹmi tẹ to si ni oun ti fi toun ra ẹrọ alupupu amunawa atawọn nkan mii fun ara rẹ.

Ileeṣẹ Ọlọpaa ni awọn afurasi yii yio foju ba ile ẹjọ nigba ti iwadii awọn ba pari.

Ẹwẹ, Komisọna Ọlọpaaa ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi kan sara si awọn ọtẹlẹmuyẹ to ṣe iṣẹ naa o si fi da awọn ara ipinlẹ Eko loju pe awọn oniṣẹ ibi yii ko ni lọ lai jiya.