Ìdí márùn-ún tí òṣèlú Tinubu fi yàtọ̀ sí tàwọn olóṣèlú míràn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gbajumọ ati ilumọọka ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu yika orilẹede Naijiria ati loke okun.

 Ọpọ ẹkun nilẹ yii, yatọ si ilẹ Yoruba to ti wa, si lo ti jẹ oye lorisirisi, oun si ni Jagaban ti Borgu

 Amọ bo se moke ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC lati di oludije aarẹ ti yoo maa soju ẹgbẹ naa ninu ibo ọdun 2023, ti mu ki okiki rẹ tun pọ si.

 Lootọ ni bo se jawe olubori ko ya ọpọ ọmọ Naijiria lẹnu bi o tilẹ jẹ pe ero awọn eeyan miran ni pe yoo fidi rẹmi ninu eto idibo abẹnu naa.

 Eyi si ri bẹẹ, ta ba wo oniruuru ọrọ odi, ibanilorukọjẹ ati atako tawọn orogun rẹ ninu ẹgbẹ oselu rẹ gbe tii, paapaa lori ayelujara.

Oselu Tinubu ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, ọjọ pẹ ti ojo ti n pa igun rẹ bọ:

 Si ọpọ eeyan, ipa ti Tinubu ti ko ninu oselu ko bẹrẹ lana, ọjọ pẹ ti ẹja nla rẹti n daamu ibu oselu lorilẹede yii.

 Koda, okiki rẹ gbalẹ to fi de ọdọ awọn mẹkunnu ni, idi si ree ti wọn se gbe oye Asiwaju fun.

 A si le sọ pe ipilẹ gbajumọ Tinubu ninu eto oselu bẹrẹ nigba to kopa ninu agbekalẹ ẹgbẹ ẹgbẹ oselu Social Democratic Party, SDP, tabi ẹgbẹ oselu ẹlẹsin.

 Lẹyin eyi lo di Sẹnetọ to lọ soju ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Eko nile asofin agba ilẹ wa lọdun 1992.

 Nigba to de ibẹ, oun lo moke lati di alaga igbimọ ile fun ọrọ ile ifowopamọ ati isuna eyi tii se igbimọ pataki nile asofin agba. 

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/Twitter

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tinubu maa n fa awọn eeyan lọwọ soke, ti yoo wulo fun lọjọ iwaju:

 Ọpọ eeyan to ba BBC sọrọ nipa idi ti oselu BolaTinubu ko se ni afiwe pẹlu tawọn oloselu to ku lo salaye pe lootọ ni Tinubu ko ni afijọ ninu oselu.

 Bala Ibrahim, tii se onwoye lagbo oselu sọ fun BBC pe ohun to daju saka, lai ni abomila ninu ni pe oselu Tinubu yatọ gedegede si tawọn oloselu yoku.

 "Asa Tinubu ni pe o maa n fa ọpọ ọdọ lọwọ soke, gbe wọn ga, awọn eeyan yii si lo maa n wulo fun lọjọ iwaju.

 Igbesẹ yii si lo yatọ si tawọn oloselu miran, ti wọn maa lo awọn eeyan lasiko ti wọn ba fẹ, ti wọn yoo si tun pa wọn ti lasiko ti wọn ko ba nilo wọn mọ.”

Tinubu ni awọn oloselu fi pamọ fun iwulo ọjọ iwaju:

 Bala Ibrahim fikun pe “Ọpọ eeyan lo maa n wo Tinubu bii ẹni ti wọn fi pamọ fun iwulo ọjọ iwaju, ọjọ iwaju naa si lo de lasiko ta wa yii.”

Bakan naa lo ni Tinubu yatọ si awọn oloselu to ku nitori o maa n setan ni gbogbo igba lati dari, ko si wa nipo iwaju ni nigbakuugba.

 "Koda , a tiẹ gbọ pe awọn ohun meremere to ti se pamọ fun ọjọ iwaju lati ẹyin wa gan lo to, to tun sẹku fun lati dide fun iranwọ rẹ lasiko yii.

 Awọn ohun to se pamọ naa si lo dide lati nu omije rẹ nu, ti wọn si n sugba rẹ lati ri daju pe ipo kan soso to n pohungbẹ rẹ to lọwọ.

Wọn gbe asia APC fun Tinubu

Oríṣun àwòrán, APC Nigeria/Twitter

Tinubu maa n na owo apo ara rẹ ati ohun gbogbo to ni lati gbe ọpọ eeyan ga:

 Bala salaye pe kii se ana ni Tinubu ti ni lerongba lati di aarẹ Naijiria, to si ti maa n sọ sita tẹlẹ laimoye igba.

 Idi si niyi to ni o se n gbe awọn lọwọ soke, maa se agbelarugẹ ọpọ eeyan fun iwulo ọjọ iwaju, awọn to mọ pe wọn yoo lee se atilẹyin fun nigba to ba ya.

 "Lasiko ti Tinubu ba n fa ọwọ awọn eeyan soke, owo apo ara rẹ ati dukia gbogbo to ni, lo maa n na.

 Ta ba si wo ibasepọ rẹ pẹlu gomina ipinlẹ Kano Abdullai Ganduje, kii se ifẹ to wọpọ kaakiri.

 Amọ Tinubu mọ pe oun nilo ibo gọbọi lati ọdọ awọn eeyan ipinlẹ Kano, nitori ipinlẹ naa lo ni iye awọn asoju-dibo to pọ julọ lasiko ibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC.”

Ta ba yọwọ Atiku Abubakar, ko tun si oloselu to lagbara mọ to Tinubu:

Nigba toun n da si ọrọ yii, onwoye oselu miran, Mahmud Jega ni ta ba yọwọ Atiku Abubakar kuro lagbo oselu Naijiria,ko tun si oloselu miran to lagbara to Tinubu.

 "Ọpọ awọn gomina tẹlẹ to ti wa nipo laarin ọdun 1999 si 2007 ni aye ti gbagbe wọn lagbo oselu.

 Amọ Bola Tinubu tubọ n lagbara siwaju ati siwaju ni lẹyin to kuro gomina ipinlẹ Eko, idi ni pe Tinubu gan jubi ju gomina miran lọ.

 Lati aye MKO Abiola si ni Tinubu ti n ni okiki amọ lẹyin ti Abiola ku tan, ko si oloselu miran to lami laaka to Tinubu mọ.

Nigba to bẹrẹ eto oselu rẹ, agbega awọn eeyan nikan lo gbajumọ, ti ko si ni ohunkohun se pẹlu titiraka lati se akoso orilẹede yii.

 Amọ nigba to ya, o bọ siwaju, ti ẹgbẹ oselu rẹ APC ati ẹya Yoruba si moke.

Ìdí nìyíí tí Buhari kò ṣe fa ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ sókè fún ipò olùdíje ààrẹ fún APC –Femi Adesina
Aworan Buhari ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina ti sọ idi ti Aarẹ Buhari ko fi yan ẹni ti yoo rọpọ rẹ le ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ.

Eyi ko ṣẹyin eto idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣẹṣẹ pari lati yan ẹni ti yoo di asia ẹgbẹ naa mu lati du ipo aarẹ ninu idibo gbogboogbo to n bọ ni ọdun 2023.

Saaju idibo naa ni Aarẹ Buhari kede pe oun ni ẹni ti oun fẹran gẹgẹ bi aayo lati di aarẹ orilẹede Naijiria lẹyin oun, ti ọpọ ero si n reti rẹ lati darukọ eniyan kan ti yoo rọpọ rẹ.

Amọ lẹyin naa ni Aarẹ kede pe ki awọn eniyan gba awọn aṣoju ‘delegates’ laaye lati yan ẹni to wu wọn lati di ipo aarẹ mu nitori oun ko ṣetan lati yan ẹni kankan le awọn ọmọ Naijiria lori.

APC Presidential Election: Buhari ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ìjọba tiwantiwa

Femi Adesina ninu awọn akọjade rẹ ti o ma n kọ lo ti fi lede idi ti aarẹ Buhari fi gbe igbesẹ yii.

O ni Buhari ṣafihan bi o ṣe jẹ akinkanju ti ko fẹran abawọn Kankan.

Bee naa lo ni eleyii ṣafihan ifẹ ijọba tiwantiwa ti Buhari ni si orilẹede Naijiria to si mu ileri rẹ ṣe pe idibo ti ko ni ni rogbodiyan ati eeru ninu ni awọn yoo ṣe ni Naijiria.

Femi adesina ni bio tilẹ jẹpe kii ṣe ẹṣẹ ni ki eniyan ni aayo bi aarẹ ṣe ni, amọ akinkanju aarẹ fi ara han nitori ko gbe agbara le ẹni naa lọwọ lọna aitọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Bakan naa lo fikun un pe ere ije naa wa laarin oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati oludije lẹgbẹ oṣelu APC , Bola Ahmed Tinubu nitori ẹgbẹ mejeeji lo ti n di ipo yii mu lati ọdun 1999.