Ọlọ́run fẹ́ gbé Ekiti gorí ẹṣin ló ṣe ní kí ń díje gómìnà nínú ẹ́gbẹ́ ẹlẹ́ṣin - Segun Oni

Àkọlé fídíò, 2022 Ekiti Governorship Election: Segun Oni ni aráàlú ló ń fẹ́ kí òun padà wá ṣe gómìnà

Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ekiti labẹ ẹgbẹ oselu Ẹlẹsin, SDP, Segun Oni ti kede pe awọn araalu lo n pariwo pe awọn n fẹ oun nipo pada ni oun se fẹ dije.

Oni, ẹni to ti se gomina nipinlẹ Ekiti lọdun mẹwa sẹyin, ni bii ba se pe awọn eeyan ipinlẹ naa n fẹ ki oun pada wa se saa keji, oun ko ba ti jade wa du ipo naa.

O ni ko si ohunkohun ti oun gbagbe sile ijọba ipinlẹ Ekiti, amọ igbe ara ilu lo n ta oun lara.

Oni, lasiko to n fọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba nibayii ti idibo gomina nipinlẹ Ekiti sunmọle, o salaye pe Ọlọrun fẹ gbe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti gun ori ẹsin lo se mu ki oun fẹ dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu ẹlẹsin.

Bakan naa lo woye pe iya ti awọn to n dari ipinlẹ naa lẹyin ti oun kuro nipo gomina kọja sisọ, o si daju pe ara awọn eeyan ipinlẹ Ekiti mọ iya pupọ.

O wa koro oju si bawọn eeyan to wa nipo akoso se n ko owo araalu na pẹlu awijare pe awn n se ijọba.

O ni gbese ti pọ ju lrun ipinlẹ naa, tawọn isẹ akanse ti wn si gba awọn gbese naa le lori, bii ipese omi ẹrọ, ko si ni aseyọri kankan.