Mo ṣelèrí láti ríi pé a yan Aàrẹ láì mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ dání ní 2023- Buhari
Ojọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993 jẹ́ ọjọ́ malegbagbe ninu iselu Naijiria- aare Muhammadu Buhari
Ojo yii ni awon eeyan Naijiria fi ara wọn han gẹgẹ bii Omoluwabi nitooto to jade sita lọ dibo laisi wahala.
Aare Muhammadu Buhari to n tuko Naijiria lọwọlọwọ salaye pe iru ọjọ yii ko wọpọ.
O so eyi lasiko to n ba awọn olugbe Naijiria sọrọ loni ayajọ ọjọ iṣelu awaarawa to jẹ eyi to maa se gbẹyin gẹgẹ bii aarẹ Naijiria.
Aarẹ bu enu ẹ̀tẹ lu awon to wa ni ijoba lasiko naa, eyi ti Ogagun Ibrahim Babangida n dari lori bi wọn se wogile abajade eto idibo naa lodun 1993.
Buhari ni pe eyi safihan ọna idari ti ko dara rara ninu eto oselu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NTA
Kini Aare Buhari tun so?
Aare Muhammadu Buhari ni pe pelu ibanuje ni oun n wa nigbagbogbo lori eto aabo Naijiria paapaa awon ajinigbe to n sose nigba gbogbo yii.
O ni oun yoo sapa oun lati rii pe eto idibo odun 2023 lọ ni irọwọrọsẹ laisi itajẹsile.
Ati pe ojutaye ni wọn yoo se gbogbo igbese naa laifi nkankan pamọ fun ara ilu.
Aare Buhari tun sọ nipa ohun to sokunfa yaajo oni ti ọpọ n pe ni June 12.
O sọ ipa ti oloogbe MKO Abiola ko ninu idibo 1993 naa.
Moshood Kashimaawo Olawale Abiola lo bori ninu idije sipo aare Naijiria lodun naa ki ijoba to wa lori aleefa to wọgilee.
Aare Buhari tun ran awọn ara ilu leti bi ijoba oun se kede ayajọ oni kuro ni ojo kokandinlogbon osu karun un, ti Naijiria maa n smai ayeye isejọba awa ara wa si oni.
O ni pe lọdun 2019 ni ijoba oun se ayipada ojo naa.
O tun gba awọn omo Naijiria nimọran lati mase gbagbe laalaaa awọn akọni isejọba awa ara wa to ti tẹrigbaṣọ.
O ni pe eyi yoo jé ki wọn woye irufẹ eni ti o yẹ lati dibo fun lọdun to m bọ.
Eto Isejoba awa ara wa ti ọdun 2022 yii ni aṣegbẹyin BMuhammadu Buhari gege bii aarẹ Naijriia.
Kini Aare Buhari tun sọ?
Buhari tun salaye pe ọrọ oni yii ni ọrọ ikẹyin oun gẹgẹ bii aarẹ Naijiria .
O ni iwoyi ọdun to m bọ, aarẹ miran ni yoo maa ka iru ọrọ yii.
Buhari ni oun si pinnu lati ri si eto aabo ki oun to kogba wọle ni 2023.












