Ìdí nìyìí tí iléẹjọ́ ní Naijiria ṣe ní kí wọ́n yẹgi fún ọ̀dọ́bìnrín yìí

Aworan Dominion to pa oga re

Oríṣun àwòrán, Google

Dominion Okoro to jẹ ọmọ Naijiria yii ni ileẹjọ paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun.

Ileẹjọ ni ilu Benin lo da ẹjọ iku naa fun un lẹyin ti wọn rii pe o jẹbi ipaniyan.

Titit di Ọjọ kọkanlelogun, Osu Kẹfa, ọdun 2022, arabinrin ẹni ọdun marunlelogun naa lo jẹ ọmọ ọdọ ni ile ilumọọkan obinrin kan ni Guusu Naijiria.

Ileẹjọ ni Okoro lo ṣekupa ọga rẹ obinrin, ẹni ọdun marunlegorin, Maria Igbinedion.

O tun jẹ iya fun gomina ipinlẹ Edo tẹlẹri, Lucky Igbinedion.

Wọn ni Dominion OKoro jẹbi ẹsun iwa ipa, ole ati ipaniyan.

Bakan naa ni ileẹjọ fun ni ẹwọn gbere nitori o tun lo oogun oloro si ara ẹni to ṣekupa naa.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Dominion Okoro to n gbe ni ọdọ ẹni to ṣekupa naa ni o jẹ ọmọ ọdọ rẹ titi di ọdun to kọja.

Ọjọ Keji, Oṣu Kejila ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Dominion Okoro pa ọga rẹ ni agbegbe GRA ni ilu Benin.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Dominion jẹwọ pe lootọ ni ohun pa mama lati ji owo rẹ ati ẹgba ọrun rẹ, to si ni ko ṣẹ oun.

O ni oru alẹ ọjọ naa ni oun fọ apoti mọ mama lori ni ibi to sun si, amọ ti ko si ẹni to gbọ.

Mama pariwo fun iranwọ amọ ọlọde nikan lo wa ni ile ti kosi gbọ igbe mama.

O ni ohun duro de nkan bi idaji ti oun si salọ pẹlu N100,000 mama ati awọn ohun ẹgba ọrun rẹ.

O ni Cross River ti oun salọ ni ọdọ ẹgbọn oun ni wọn ti ri oun mu.

Awọn ẹbi Igbinedion naa ni o tipe to ti wa ni ọdọ wọn, ti wọn si ti ri gẹgẹ bi ọmọ wọn to n tọju mama agba, ko to dipe o wa pa mama.