Ẹ fura o! Ilé aṣòfin ké gbàǹjarè sí iléeṣẹ́ ológun lórí àwọn agbéṣùmọ̀mí tó ń kọ ibùdó sí Kwara àti Niger

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Nàìjíríà ti ké gbàǹjarè sí iléeṣẹ́ ológun láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí bí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ti ń fi àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Kwara àti Niger ṣe ibùjókòó.
Ìfẹnukò ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láti tètè ta iléeṣẹ́ ológun ní olobó lórí ìpèníjà ààbò ní agbègbè omi odò Kainji kò ṣẹ̀yìn àbá kan tó dá lórí bí àìsí ètò ààbò ní agbègbè ṣe jẹ́ ìpèníjà ńlá fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama, Baruten àti Borgu ní ìpínlẹ̀ Kwara àti Niger.
Níbi ìjíròrò ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà ní àwọn ọmọ ilé ti pe àkíyèsí iléeṣẹ́ ológun wí pé àwọn agbébọn ti ni ibùdó ní àwọn ìlú tó wà ní agbègbè odò Kainji.
Ìjíròrò ọ̀hún wáyé nígbà tí aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn àríwá Kwara, Sadiq Suleiman Umar tẹ́ pẹpẹ àbá lórí ọ̀rọ̀ náà síwájú ilé tí Aliyu Sabi Abdullahi láti ìpínlẹ̀ Niger náà sì kin lẹ́yìn.
Sadiq ní àwọn agbébọn àti àwọn agbéṣùmọ̀má ọ̀hún ti ni bùba ní àwọn ìlú bíi Kaiama, Karonzi-Yashikira ní ìpínlẹ̀ Kwara àti ìlú Wawa àti Babana ní ìpínlẹ̀ Niger tí èyí sì jẹ́ ewu ńlá fún àwọn ènìyàn tó ń gbé agbègbè náà.
Ó ní inú fu, àyà fu ni àwọn ènìyàn agbègbè náà fi ń gbé báyìí nítorí ìbẹ̀rùbojo pé kí wọ́n má pa àwọn tàbí jí àwọn gbé lọ.
Ó ní gbogbo inú igbó kìjikìji tí ìjọba ṣàgbékalẹ̀ láti wà gẹ́gẹ́ bí ohun ìnàjú fún àwọn ènìyàn ni àwọn agbébọn ti sọ di ilé báyìí láti máa fi wùwà aburú wọn.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn aṣọ́gbó tó wà ní níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni agbára wọn kò ka mọ́ nítorí wọ́n ti pàdánù gbogbo igbó náà sọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Sadiq tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń gbé ní agbègbè yìí ló jẹ́ àgbẹ̀ pọ́ńbélé, tí wọn kò sì le ṣe iṣẹ́ oòjọ́ wọn mọ́ nítorí ìdúnkokò àwọn ọ̀daràn tó ti yí wọn ká.
Bákan náà ló ní ọ̀pọ̀ wọn ló ti ń fi ìlú wọn sílẹ̀ láti sálọ sí ìgboro tí èyí sì lè fa kí àlékún bá ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí ìkọlù yóò máa wáyé ní agbègbè yìí
“Àwọn mìíràn ti ẹ̀ ti ń fún àwọn ọ̀daràn náà lówó bíi ìṣákọ́lẹ̀ kí wọ́n le máa rí ìlú wọn ní àláfíà.”
Ó tún ṣèrántí pé ní ọdún 2008 ni àwọn agbébọn kọ́kọ́ ṣe ]ikọlù sí àwọn fijilanté ní agbègbè náà àti pé ní ọdún 2022 yìí nìkan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjínigbé ló ti wáyé ní àwọn ìlú bíi Nanu, Nuku, Woro àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé náló pàdánù ẹ̀mí wọn tí àwọn tí wọ́n sì tú sílẹ̀ san owó iyebíye kí wọ́n tó gba ìtúsílẹ̀.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin wá rọ ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ààbò láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ológun kí wọ́n le dá ikọ̀ “Forward Operation Base” kalẹ̀ sí àwọn agbègbè náà.
Bákan náà ni wọ́n rọ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA, láti fi ohun èlò ránṣẹ́ sí àwọn tó ti lùgbàdì ìkọlù àwọn ọ̀daràn náà.












